Wọn tun fi awọọdu ara-ọtọ da ileeṣẹ Pelican lọla - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, December 23, 2022

Wọn tun fi awọọdu ara-ọtọ da ileeṣẹ Pelican lọla


Ko digba ti eeyan ba pariwo ara rẹ, tabi iṣẹ to n ṣe lori redio ati tẹlifiṣan kaakiri, ki aye too mọ ipa to n ko ninu eto idagbasoke ilu ati orileede yii, iṣẹ rẹ ni yoo maa fọhun kaakiri.
 
Ọkan pataki lara awọn to n mu idagbasoke ati ilọsiwaju ba eto ọrọ aje ipinlẹ Ogun, paapaa orileede Naijiria ni Ọmọwe Babatunde Adeyẹmọ, alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ Pelican Valley Estate.

Ọmọwe Adeyẹmọ, ẹni to ti figba kan ri jẹ akọroyin lo ti fi iwa oju aanu rẹ, nipa ileeṣẹ to da silẹ lati fi ṣe iranlọwọ f'awọn eeyan, paapaa awọn ti wọn ko lero wi pe wọn yoo di lanlọọdu nigbesi aye wọn, ni wọn ti di onile lori.

Laipẹ yii ni ẹgbẹ Nigerian Institute of Town Planners (NITP), ẹka ti ipinlẹ Ogun fi aami ẹyẹ ti ko wọpọ da Ọmọwe Babatunde Adeyẹmọ lọla, gẹgẹ bi ọkan pataki lara awọn to yan iṣẹ ilẹ ati ile tita laayo n'ipinlẹ naa.
 
Iwadii ti ileeṣẹ AWIKONKO ṣe fi ye wa pe lati bi ọdun mẹwaa le diẹ sẹyin ti ileeṣẹ Pelican Valley Estate ti wa, titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, ko tii s'ẹni to fẹsun kan wọn tabi gbe wọn lọ sile ẹjọ.
 
A gbọ pe nipa iwa otitọ ati iwa ọmọluabi ni wọn fi n b'awọn eeyan dowopọ, lori ọrọ ilẹ ati dukia tita. Eyi si jẹ koko pataki ti wọn fi n gba aami ẹyẹ kaakiri.

Bi a ba si bu kere, awọọdu ti ẹgbẹ Nigerian Institute of Town Planners (NITP) si fi da ileeṣẹ Pelican lọla ni yoo jẹ ikẹrinlelogun ti wọn yoo gba laaarin oṣu meji lera wọn. Ko si nnkan meji to fa a, bi ko ṣe otitọ ti wọn n ṣe.
 
Nibi eto awọọdu naa, alaga ẹgbẹ Nigerian Institute of Town Planners (NITP), Arabinrin Oyeyinka Adenẹkan ṣapejuwe Ọmọwe Adeyẹmọ gẹgẹ bii aṣoju iwa otitọ si kikọ agbegbe alaafia, iyẹn 'ambassador for quality - built environment' n'ipinlẹ Ogun.

Nibẹ ni wọn tun ti fun un ni iwe ẹri  idupẹ, fun bo ti ṣe n tukọ ileeṣẹ rẹ lai labawọn.
 
Ọmọwe Adeyẹmọ ni oludasilẹ ati alaṣẹ ileeṣẹ Pelican Valley Nigeria Ltd; the proprietor of Pelican Valley Estate, Pelican - Brief Estate, Pelican Ecostay Apartment ati Pelican' Greenish Acres Farm Estates to wa niluu Abẹokuta si Kobape ati Masa, nipinlẹ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI