Gbogbo awọn ara ati olugbe ilu Orile Ilawọ to wa n'ijọba ibilẹ Ọdẹda ipinlẹ Ogun ni wọn ti rawọ ẹbẹ si Gomina Dapọ Abiọdun lati bu ọwọ lu Olunla tilu Ilawọ, Oloye Oluṣẹgun Alexander Macgregor gẹgẹ bi ọba ti wọn n fẹ.
Wọn ni Oloye MacGregor nikan l'awọn mọ gẹgẹ bi ojulowo ọba ti yoo tu gbogbo ilu naa ati agbegbe rẹ lara, paapaa nipa idagbasoke ati ilọsiwaju ti ko lẹgbẹ.
Laipẹ yii ni AWIKONKO lọ siluu Orile Ilawọ bii Alagbagba, Ẹlẹgunmẹfa ati agbegbe rẹ lati fi ọrọ wa awọn araalu lẹnu wo, lati mọ ẹni ti wọn n fẹ gẹgẹ bi ọba, ati iranlọwọ ti wọn n fẹ lati ọdọ ijọba ipinlẹ Ogun labẹ Gomina Dapọ Abiọdun.
Awọn ọmọde, agbalagba, onile, alejo, ọkunrin ati obinrin ni wọn fi inu didun ṣalaye pe ko si ẹni meji ti awọn n fẹ, to kọja Oloye Alexander MacGregor lati di ọba wọn.
Yatọ si awọn to ba wa sọrọ, awọn oloye to fi mọ Baalẹ ilu ni wọn fi idaniloju han pe bi MacGregor ba fi jẹ ọba wọn, inu igbadun ayeraye l'awọn yoo wa, ti ilu naa yoo si dabi Lọndọọnu laipẹ.
Lara awọn to b'AWIKONKO sọrọ jẹ ko ye wa pe baba to bi Oloye Oluṣẹgun MacGregor, iyẹn Oloye Oloogbe Bisi MacGregor lo gbe ade ọba wọnu ilu naa, bo tilẹ jẹ pe baba naa kọ lo pada jẹ ọba ọhun, , sibẹ, awọn gbọdọ fi ẹmi imoore han fun ọmọ rẹ lati jẹ ọba le wọn lori.
Wọn ni lati bi ọdun mẹẹdogun sẹyin ni Alexander MacGregor ti n mu idagbasoke ba ilu, to si n gbe iranlọwọ dide f'awọn ọmọ ilu, eyi ti wọn lo di dandan wi pe k'awọn naa ṣatilẹyin fun un lakoko yii.
Bo tilẹ jẹ pe kii ṣe Oluṣẹgun MacGregor nikan lo n du ipo ọba ọhun, marun-un ni gbogbo awọn to jade lati di ọba ilu Orile Ilawọ, ṣugbọn to ti da oriṣirṣi awuyewuye silẹ.
B'awọn kan ṣe n sọ pe Alexander MacGregor l'awọn n fẹ n'ipo, bẹẹ lawọn miran n sọ pe Oloye Bada lawọn n fẹ, ti awọn miran si n sọ pe Ogunsanya ni ti wọn, ati bẹẹbẹẹlọ.
Iwadii ti ikọ AWIKONKO ṣe lọ si gbogbo abule to so ilu Ilawọ papọ laipẹ yii ni wọn ti fi da wa loju pe Alexander MacGregor nikan ni ẹni ti wọn mọ julọ ninu awọn ọmọ oye naa, ti wọn si loun nikan lo kaju oṣuwọn lati di ọba wọn.
Wọn jẹ ko ye wa pe gbogbo awọn to n fapajanu latigba ti ijọba ibilẹ Ọdẹda ti kede MacGregor gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori fun ipo ọba, ni wọn sọ pe ajagungbalẹ ni wọn, ati pe ilẹ ilu ti wọn n ta lo mu ki wọn fẹẹ de ipo ọba ni tipatipa.
Lara awọn to jade du ipo ọba Ilawọ naa ni Ṣowunmi Joseph, Fatai Ṣodimu, Oluṣẹgun MacGregor, Lawrence Ogunsanya ati Adio Ọmọgoriọla Ṣodipọ.
Gbogbo awọnn to ba AWIKONKO sọrọ patapata ni wọn tọwọ bọwe idaniloju, iyẹn eyi ti oloyinbo n pe ni 'Vote of Confidence' fun Alexander MacGregor, ti wọn si n rawọ ẹbẹ si gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun lati tete b'awọn bu ọwọ lu ẹni ti ilu n fẹ n'ipo ọba.
A gbọ pe kii ṣe MacGregor lo deedee dide lati du ipo ọba, bi ko ṣe pe awọn ọmọ ilu ti wọn mọ ipa ti yoo ko ninu idagbasoke to ba jẹ ọba ni wọn lọ gbe e dide, koda wọn ni pẹlu ẹbẹ ni wọn fi pe Oloye Olunla Ilawọ naa lati wa di ọba wọn.
Ọnarebu Musiliu Abiọla, Arabinrin Kafayat Adedapọ, Arabinrin Adebọla Adegbitẹ, Arabinrin Taiwọ, Arabinrin Atọbatẹlẹ, Ọgbẹni Ọlajide Musiliu, Arabinrin Aishat Arowora at'awọn miran ni wọn sọ pe ẹnikan ṣoṣo t'awọn le fọwọ rẹ sọya fun ipo ọba naa ni Olunla, Oloye Ọmọọma Alexander MacGregor.
No comments:
Post a Comment