2023: AbdulRazaq gbe eto tuntun kalẹ fun idagbasoke ipinlẹ Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, January 3, 2023

2023: AbdulRazaq gbe eto tuntun kalẹ fun idagbasoke ipinlẹ Kwara


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti sọ pe oun ti gbe ilana tuntun kalẹ lati mu idagbasoke ati ilọsiwaju alailẹgbẹẹ ba ipinlẹ naa l'ọdun 2023, to si ni gbogbo ohun toun ba dawọle pata ni yoo ṣanfaani f'araalu.
 
AbdulRazaq lo sọ eyi di mimọ ninu eto ati ilana, paapaa ipinnu tuntun f'ọdun 2023 ninu ọrọ rẹ to fi n ki awọn eeyan ku ayẹyẹ ọdun tuntun.
 
Nibẹ lo ti sọ pe iṣakoso oun yoo tubọ maa gbe awọn eto ati ilana ọlọkan-o-jọkan  fun idagbasoke kalẹ, eyi ti yoo maa mu anfaani tuntun wa f'awọn araalu.
 
O ni ọdun tuntun yii lawọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ naa yoo ṣe ipinnu tuntun lati yan awọn adari tuntun ti wọn nigbagbọ ninu wọn fun itẹsiwaju iṣẹ idagbasoke
 
AbdulRazaq gba awọn araalu lamọran lati ma ṣe ṣiṣe nipa yiyan awọn adari tuntun, to si ni bi wọno ba ṣiṣe, wọn yoo tun duro ọdun mẹrin miran, ki wọn to le ni itẹsiwaju.
 
Siwaju sii lo gbadura fun gbogbo araalu wi pe ọdun 2023 yoo jẹ ọdun idunnu ati ayọ, eyi ti awọn eeyan yoo ti jé igbadun mudunmudun eto oṣelu awaarawa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI