Gbajugbaja oṣere tiata nni, Yọmi Gold ti kede wi pe igbeyawo oun pẹlu Meenah ti fọroṣanpọn, awọn si ti pin gaari.
Yọmi lo kede sita fun gbogbo eeyan, paapaa awọn ololufẹ rẹ kaakiri agbaye wi pe ibagbepọ oun pẹlu Meenah ko le tẹsiwaju m,ọ, nitori awọn kudiẹ-kudiẹ to n ṣẹlẹ laaarin wọn.
Nigba to n kede lori ikanni Instagiraamu rẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee to kọja, o ṣalaye pe iyawo oun ko yẹ lẹni to n fẹ iru ọkunrin bii toun silẹ, to si loun ṣetan lati jẹ ki ololufẹ oun jẹ eeyan pataki.
"Emi ati Meenah ti pinnu lati lọ lọtọọtọ..Mo fẹẹ sọ fun awọn ẹbi, ọrẹ ati ololufẹ wa mọ, ki wọn si jẹ ki ọrọ wa ye wọn. Asiko yii kii ṣe lati da ẹjọ fun ẹnikẹni.
"Nigba ti ifẹ ba ti ku ninu ibaṣepọ. Ẹnikẹni ko gbọdọ fi ipa mu un. Mo fẹẹ fi asiko yii dupẹ lọwọ gbogbo eeyan ti wọn dide si ọrọ wa.
"Eeyan daadaa ni Meenah jẹ.. ko si yẹ lẹni to n fẹ iru ọkunrin bii t'emi. O maa ri ọkunrin ati ololufẹ to dara ju emi lọ.
"Mi o pe gẹgẹ bi ẹlẹran ara.. Maa si ṣiṣẹ fun ara mi lati jẹ eniyan to dara.
"A ni lati gbe eyi jade nitori pe a fẹ ki gbogbo eeyan mọ nipa wa, ati nipa igbesẹ ti a gbe yii. Igba yoo si dara siwaju sii."
No comments:
Post a Comment