A dupẹ pe Ọlọrun ti ba wa le igi wọrọkọ Jimi Lawal danu lẹgbẹ ọsẹlu PDP - Aderinokun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 26, 2023

A dupẹ pe Ọlọrun ti ba wa le igi wọrọkọ Jimi Lawal danu lẹgbẹ ọsẹlu PDP - Aderinokun


Gbajugbaja oloṣelu nni to n du ipo ile igbimọ aṣofin agba lorileede yii, Olumide Aderinokun ti sọ pe ọpẹ nla lo jẹ fun wọn wi pe Ọlọrun ti ba wọn le igi wọrọkọ Jimi Lawal to n da wahala silẹ ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP n'ipinlẹ Ogun danu.

Aderinokun to n dije lẹkun aarin gbungbun ipinlẹ naa labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP lo sọrọ yii lakoko to n ba ileeṣẹ iroyin BBC YORUBA sọrọ niluu Abẹokuta laipẹ yii.

O ni ohun to jẹ iyalẹnu fun wọn ni pe ko tii ju ọsẹ meje ki wọn ṣe idibo abẹnu lẹgbẹ naa ti Jimi Lawal fi de, to si ni kaka ko farabalẹ, niṣe lo sọ pe oun fẹẹ du ipo gomina.

Aderinokun sọ pe ẹni ti ko mọ bi nnkan ṣe n lọ lẹgbẹ naa, bawo ni yoo ṣe sọ pe oun l'awọn ọmọ ẹgbẹ n fẹ lati ṣoju wọn fun ipo gomina.

O ni ko tiẹ ro ipa ti oludije sipo gomina lẹgbẹ naa, Ọnarebu Ọladipupọ Adebutu ti ko, ẹni to sọ pe o n na owo sinu ẹgbẹ, to si fẹẹ sare wa jẹ gaba lee lori.
 
Ninu ọrọ rẹ, o ni 
"Jimi Lawal kan wa ba nnkan jẹ ni. Ṣe ẹ mọ pe lọdun 2019, Ọgbẹni Jimi Lawal o ṣi lọ sinu ẹgbẹ APC lati lọ fa wahala. Wahala to fun wa lakoko idibo yii lo fun awọn ẹgbẹ APC naa nigba ti wọn ṣe idibo abẹle lọdun naa lọhun.
 
"Mi o mọ beeyan ṣe maa wa lati Kaduna, ẹni to n ba gomina ipinlẹ Kaduna ṣiṣẹ tẹlẹ. Igba to maa sare wa s'ipinlẹ Ogun, ko ju bi ọsẹ meje ka ṣe idibo abẹle lọ lo de. O wa sọ pe oun fẹẹ bori nibi idibo abẹle naa.
 
"O loun fẹẹ na Ladi Adebutu nibi idibo abẹle wa, Ladi Adebutu to jẹ pe oun lo n gbe ẹgbẹ oṣelu PDP wa, oun lo n na gbogbo owo kọọti ti PDP n lọ. Iwọ wa sare wa wi pe o fẹẹ bori nibi idibo abẹle ti a ṣe.
 
"Gbogbo asiko ti a n sọ yii, Jimi Lawal ṣi n ṣiṣẹ nipinlẹ Kaduna, o si tun n gba owo oṣu lọwọ ijọba Kaduna labẹ ẹgbẹ oṣelu APC. Lọkan t'emi, mo ro pe Jimi Lawal kan fẹ wa ba iṣẹ wa jẹ lasan ni, ṣugbọn a dupẹ fun Ọlọrun, nitori pe Ọlọrun ti ba wa lee lọ."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI