Imaamu agba ilu Ọyọ jade laye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 26, 2023

Imaamu agba ilu Ọyọ jade laye


Imaamu agba n'iluu Ọyọ, Sheikh Mashood Abdul Ganiyy Adebayọ Ajokidero kẹta ti jade laye.
 
AWIKONKO gbọ pe aarọ oni, Ọjọbọ tii ṣẹ Tọsidee ni Imaamu agba naa gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra.

Ọkan lara awọn to sunmọ ẹbi naa, to ba akọroyin sọrọ ṣalaye pe agba Imaamu naa jade laye lẹyin aisan rampẹ.
 
“As salaam alaykum. InnaLillah wainna Ilaihu raajiun. A n fi asiko yii kede ipapoda Imaamu agba ilu Ọyọ. Ki Allah tẹ si afẹfẹ rere. Amin”.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI