Awọn agbebọnrin tun ti ji ọba alaye gbe oooo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 26, 2023

Awọn agbebọnrin tun ti ji ọba alaye gbe oooo


Awọn agbebọnrin tun ti ji ọba alaye, Joshua Ahmadu gbe n'ipinlẹ Kaduna, ti ko si tii le sọ pato ibi ti wọn gbe kabiyesi naa lọ titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii.
 
Olori agbegbe Chawai to wa n'ijọba ibilẹ Kauru, ipinlẹ Kaduna ni wọn pe Ahmadu.
 
Abel Adamu, to jẹ aarẹ ẹgbẹ idagbasoke agbegbe naa, Chawai Development Association, CDA, lo f'idi iṣẹlẹ naa mulẹ l'Ọjọru, Wẹsidee, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu kinni, ọdun 2023 ti a wa yii.
 
Adamu lo sọrọ naa ninu atẹjade ti agbẹnusọ wọn, Rapeahl Joshua fi sita, to si jẹ ko di mimọ pe alẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee ọsẹ yii ni wọn ji ọba alaye naa gbe ninu ile to wa ni Zambina.
 
Nnkan bi aago mẹsan aabọ alẹ ni wọn sọ pe awọn agbebọnrin naa yawọ aafin kabiyesi yii pẹlu ibọn atawọn nnkan ija oloro, ti wọn si gbe e lọ.

Aarẹ agbegbe naa wa sọ pe igbesẹ ti n lọ lati rii pe wọn gba a silẹ lọwọ wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI