Awọn alaṣẹ CBN ṣabẹwo ibanikẹdun si awọn mọlẹbi tọkọtaya ti wọn dana sun l'Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 5, 2023

Awọn alaṣẹ CBN ṣabẹwo ibanikẹdun si awọn mọlẹbi tọkọtaya ti wọn dana sun l'Abẹokuta


L'Ọjọru, Wẹsidee ana ni awọn alakoso banki agba orile-ede Naijiria, Central Bank of Nigeria (CBN) ṣabẹwo ibanikẹdun si awọn mọlẹbi tọkọtaya ti awọn amookunṣeka pa, ti wọn si tun dana sun niluu Abẹokuta loru aisun ọdun tuntun ti a wa yii.

Tọkọtaya naa, Ọgbẹni Kẹhinde Fatinoye to jẹ ọga agba lẹka eto ipawowọle (Marketing Manager)  ati Arabinrin Olubukọnla Fatinoye toun naa jẹ oṣiṣẹ fasiti ọgbin l'Abẹokuta, FUNAAB l'awọn agbebọn ṣe ikọlu si ile wọn, ti wọn si tun lọ ju ọmọ wọn ati alabagbe wọn sodo.

Iroyin aburu naa l'awọn eeyan ṣi n sọ titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, nitori pe kayeefi lo n jẹ.

AWIKONKO rii gbọ pe nnkan bi aago mejila aabọ ọsan ni awọn alakoso banki agba naa de ile awọn oloogbe yii to wa lagbegbe GRA, Ibara niluu Abẹokuta.

Bọọsi bọginni nla ti nọmba idanimọ rẹ jẹ 10L289FG ni a gbọ pe awọn alakoso naa gbe wa lati ba awọn mọlẹbi tọkọtaya naa kẹdun.


Gbara ti wọn de ile naa, inu ọgba ile to wa niwaju ile awọn oloogbe yii ni wọn wọ lọ lati ṣe ipade papọ pẹlu awọn mọlẹbi.

Mọlẹbi Oloogbe Kẹhinde ati mọlẹbi Oloogbe Olubukọnla la gbọ pe awọn alakoso CBN ọhun ṣe ipade apapọ pẹlu, nibi ti wọn ti kọminu lori iṣẹlẹ naa, ti wọn si ṣeleri wi pe awọn yoo ṣe atilẹyin to ba yẹ fun wọn.

Nibi ipade ọhun ni Ọgbẹni Christopher Ṣomide ati Jinmi Bajẹla ti sọrọ lorukọ mọlẹbi mejeeji, ti wọn si jẹ ko di mimọ pe iṣẹlẹ naa ba wọn lọkan jẹ pupọ.

Alakoso to lewaju igbimọ alakoso CBN naa, ẹni to kọ lati darukọ ara rẹ sọ pe wiwa ti awọn wa, ko ṣẹyin aṣẹ Gomina banki agba ọhun, Godwin Emefiele.


Alakoso ti awọn oṣiṣẹ banki agba ọhun lati Abuja, Eko ati Abẹokuta kọwọrin pẹlu rẹ sọ fi ye ipade naa wi pe adanu nla ni iku Ọgbẹni Kẹhinde Fatinoye jẹ fun wọn

O ṣapejuwe oloogbe naa gẹgẹ bii alabaṣiṣẹpọ to ni iwa irẹlẹ, to si fẹran alaafia, ati pe ko fẹran ki eeyan baa banujẹ nitosi rẹ, ti yoo si ṣe iranwọ to ba yẹ.

Siwaju sii lo sọ pe oun nigbagbọ wi pe gbogbo awọn to lọwọ si iku awọn oloogbe naa lọwọ maa tẹ laipẹ lati foju wọn winna ofin, ti idajọ ododo yoo si waye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI