Ẹ wo tọkọ-taya to ta ọkan iyaale ni ẹgbẹrun lọna aadọta naira, ati ẹsẹ rẹ lẹgbẹrun lọna ọgbọn naira l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 5, 2023

Ẹ wo tọkọ-taya to ta ọkan iyaale ni ẹgbẹrun lọna aadọta naira, ati ẹsẹ rẹ lẹgbẹrun lọna ọgbọn naira l'Ogun


Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ awọn mẹfa kan lori ẹsun wi pe wọn pa iyaale ile, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn kan, Oyindamọla Adeyẹmi, wọn si yọ awọn ẹya ara rẹ lati fi ṣetutu.
 
Oyindamọla, ọlọmọ meji naa la gbọ pe ọrẹkunrin rẹ tan lọ sile rẹ lati pa, nibi ti wọn ti kun ẹyta ara rẹ si wẹwẹ.
 
A gbọ pe ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kejila, ọdun to kọja ni Oyindamọla kuro nile, ti ko si pada lasiko to yẹ ko pada, eyi to mu k'awọn ti wọn jọ n gbe ile bẹrẹ sii pe ẹrọ ibanisọrọ rẹ lati mọ ibi to wa, ṣugbọn ti ko lọ.
 
Ẹrọ ibanisọrọ naa ti ko lọ lo mu ki ọkan lara awọn ti wọn jọ n gbe, Ojo Ọmọlara lọ fi to awọn ọlọpaa ẹkun Ọbalende to wa niluu Ijébu-Ode leti wi pe awọn n wa iyaale ile kan, Oyindamọla lorukọ rẹ.
 
Awọn ọlọpaa nigba ti wọn gbọ, sọ pe ki wọn ṣi maa lọ sile naa, nitori to ṣee ṣe ko jẹ o rin irin ti ko fẹ ki ẹnikẹni mọ, ati pe ko tii to wakati mẹrinlelogun, ti awọn le fi bẹrẹ igbesẹ lati wa a.

Lẹyin wakati mẹrinlelogun ti wọn ko rii, ni Ọmọlara tun gba teṣan naa lọ lati fi to wọn leti, to si jẹ pe loju ẹsẹ ni wọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii wọn.
 
Ọjọ naa, to jẹ ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kejila, ọdun 2022 ni wọn lawọn kan ta ileeṣẹ ọlọpaa lolobo wi pe awọn ri oku ẹnikan ti wọn ti yọ ẹya ara rẹ lọ, eyi lo mu k'awọn ọlọpaa lọ sibẹ, ti wọn si ri pe otitọ ni.
 
Awọn ọlọpaa lo pada gbe oku naa lọ si mọṣuari.
 
Mọṣuari ọhun ti wọn sọ pe ko jinna si ile ti Ọmọlara n gbe, ni wọn lawọn to gbọ pe wọn n wa Oyindamọla sare lọ pe awọn araale lati wa wo oku ti wọn gbe wa si mọṣuari awọn, boya oku naa jọ ẹni ti wọn n wa.
 
Wọn ko fi ọrọ naa falẹ rara ti wọn fi sare lọ sibẹ, to si jẹ iyalẹnu lo jẹ pe ẹni ti wọn n wa ni wọn ri oku rẹ, ti wọn tun ti ge ori rẹ lọ.
 
Awọtẹlẹ to wọ jade la gbọ pe wọn fi da a mọ, nitori pe wọn ti ge ori, apa ati ẹsẹ lọ, koda wọn tun yọ ọkan rẹ lọ pẹlu.
 
Lẹyin eyi ni wọn gba teṣan ọlọpaa naa lọ pada wi pe ẹni ti wọn n wa ni wọn ti ge ori rẹ lọ. Eyi lo jẹ k'awọn ọlọpaa tẹra mọ iwadii wọn.
 
Ninu iwadii ọlọpaa ni wọn ti tọpinpin foonu Itel ti Oyindamọla nlo, de ile babalawo kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Taiwo Olutufẹṣe Ajalọrun, ẹni ti wọn loun ni ọrẹkunrin Oyindamọla l'Ọjọru, Wẹsidee, ọjọ kẹrin, oṣu kinni, ọdun 2023 ti a wa yii.
 
Loju ẹsẹ ti wọn de ile Taiwo ni wọn ti yẹ gbogbo inu ile rẹ wo, nibi ti wọn ti ba ike nla kan to kun fun ẹjẹ, eyi ti igbagbọ wa wi pe ẹjẹ Oyindamọla ni.

Bi wọn ṣe mu Taiwo, naa ni wọn tun mu iyawo rẹ, Salawa Oyenusi Ajalọrun pẹ;lu, ko to di pe ọwọ tun tẹ Lukman Ọladele, ẹni ti wọn loun lo ko ẹsẹ oloogbe naa ti wọn ge dani.

Ninu ọrọ ti Taiwo ati Lukman sọ, wọn l'awọn mejeeji lawọn tan Oyindamọla lọ sile Taiwo to jẹ ololufẹ ikọkọ rẹ. Bo si ṣe wọle ni wọn ti fun un lọrun pa, ko to di pe wọn bẹrẹ sii kun ẹya ara rẹ si wẹwẹ.
 
Koda, wọn jẹ ko di mimọ pe loju ẹsẹ l'awọn ti ta awọn ẹya rẹ f'awọn onibara awọn. Wọn ni ẹgbẹrun lọna ọgbọn (N30,000) naira lawọn ta ẹsẹ rẹ, nigba ti awọn ta ọkan rẹ ni ẹgbẹrun lọna aadọta (N50,000) naira fun ẹnikan ti wọn pe ni Akeem Bello, ẹni ti wọn loun naa ti wa lahamọ ọlọpaa bayii.
 
Wọn jẹwọ pe etutu ọla ni wọn fẹẹ fi awọn ẹya ara Oyindamọla ṣe.
 
Siwaju sii ni wọn tun jẹwọ pe Oyindamọla ni ẹnikẹta ti awọn yoo pa nipakupa bẹẹ lati fi ṣetutu owo.
 
Awọn miran ti ọwọ tun tẹ ni Kayọde Ibrahim, Alebioṣu Adebayọ, Fatai Rasheed ati Fatai Jimọh.
 
Ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankọle ti wa paṣẹ pe ki iwadii kikun tubọ tẹsiwaju lori iṣẹlẹ naa, ki wọn le f'oju awọn to ba jẹbi ba ile-ẹjọ fun idajọ ododo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI