Ọmọ Yoruba atata ni mi, idi ti mo fi n sọ ijinlẹ Yoruba niyẹn - Adejọbi, Alukoro agba fun ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 5, 2023

Ọmọ Yoruba atata ni mi, idi ti mo fi n sọ ijinlẹ Yoruba niyẹn - Adejọbi, Alukoro agba fun ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria


Alukoro agba fun ileeṣẹ ọlọpaa orileede Naijiria, Ọmọọba Olumuyiwa Adejọbi ti sọ pe ọpọ awọn eeyan ni wọn ti gbagbe pe Ọmọọba loun, toun si dagba sinu aafin.

Adejọbi sọ pe pupọ awọn ti gbagbe pe inu aafin toun gbe dagba, ati imọ ẹkọ toun kọ nipa Archaeology ni fasiti Ibadan lo fa a toun fi gbọ ijinlẹ ede Yoruba.

Iyẹn nikan tun kọ, Adejọbi sọ pe yatọ si ẹkọ toun kọ ni fasiti Ibadan, baba oun naa, Ọba Adejọbi kẹkọọ nipa imọ ede Yoruba ni fasiti Eko, iyẹn Unilag.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe
"Ọpọ awọn eeyan lo ti gbagbe pe Ọmọọba to dagba sinu aafin ni mi. Mo kẹkọọ nipa imọ Archaeology ni UI, ati pe baba mi, Ọba Adejọbi, Olowu, kẹkọọ imọ ede Yoruba ni Unilag.

"Ọmọ ọdun mẹrin ni mo wa nigba ti baba mi gun ori itẹ gẹgẹ bi Olowu ti Orile Owu. Ọmọ ijinlẹ Yoruba ni mi, mo si mọ nipa iṣe, iṣẹṣe ati ẹwa ede Yoruba.

"Idi ree  to fi jẹ pe bi mo ba n sọrọ nipa iṣẹṣe ati ohun to jẹ otitọ nipa Yoruba, igbagbọ ati ohun ti ẹmi, bi ẹ ki ba n ṣe agbalagba, ẹ ma ṣe gbiyanju lati tako ohun ti mo ba sọ, nitori pe o ṣee ṣe ki ẹ ma ni iriri tabi ipilẹ ohun ti ẹ maa fi dahun si ọrọ mi.

"Ọmọ Yoruba atata ni mi oo. Ọgbọn mbẹ, imọ wa, bẹẹ si ni eeyan wa. Ẹ lọ kọ nipa aṣa. Ire o."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI