Awọn ọmọ mi ni ko jẹ ki n ni ọkọ miran - Gbajugbaja agba oṣere oloyinbo nni - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, January 22, 2023

Awọn ọmọ mi ni ko jẹ ki n ni ọkọ miran - Gbajugbaja agba oṣere oloyinbo nni


Ilu-mọ-ọn-ka agba oṣerebinrin nni, Patience Ozokwo ti sọ pe gbogbo igbesẹ toun gbe lati ni ọkọ miran lẹyin ti ọkọ oun ku lo ja si pabo, nitori pe awọn ọmọ oun lo sọ pe awọn yoo ṣe bi ọkọ foun, to si ni wọn mu ileri naa ṣẹ.

Agba oṣere naa lo tu aṣiri yii l'Ọjọbọ, Tọsidee to kọja yii nibi eto ọlọsẹ-ọsẹ ti gbajumọ oṣerbinrin nni ti maa n se ounjẹ, Mercy Johnson, eyi to pe ni Mercy’s Menu

O ni “Mo fẹẹ ni ọkọ miran, ṣugbọn awọn ọmọ mi ti dagba, wọn si bẹ mi pe ki n ma ṣe ni ọkọ miran, wọn si ṣeleri fun mi pe wọn maa ṣe ọkọ fun mi.

“Wọn ni ki n wa bi mo ṣe wa nitori pe ki awọn ọrẹ wọn ma ba maa fi wọn ṣẹlẹya, wi pe pẹlu bi ọjọ ori awọn ṣe to, mama awọn ṣi tun n ni ọkọ, ọrọ wọn si ye mi yekeyeke.
 
“Bo tilẹ jẹ pe ti ara wọn nikan ni wọn mọ, ṣugbọn mo ṣe akikanju, mo si duro lori ipinnu nla ti wọn fẹ naa
.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI