Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq laipẹ yii ti sọ pe iṣẹ rere toun n ṣe nipinlẹ naa lo n tọ oun ati iṣakoso lẹyin, idi ti oriṣiriṣi anfaani ṣe n yọju foun.
AbdulRazaq lo sọrọ naa niluu Ilọrin, lakoko ti igbimọ iṣakoso ileeṣẹ iwe iroyin Vanguard ṣe abẹwo sii lati fun un niwe ipe gẹgẹ bi ọkan lara awọn gomina to ṣe daadaa julọ lọdun 2022 to kọja.
Nigba to n sọrọ, o loun ri i daju pe awọn ohun to ṣe pataki si ọpọ awọn araalu ipinlẹ naa loun n ṣe. O ni lẹka eto ẹkọ, eto ilera, ipese omi ẹrọ igbalode, opopona to ja geere lawọn ti fọwọ kan, fun irọrun araalu.
O ni pupọ awọn nnkan toun ṣe lo ṣee foju ri, ti wọn si le jẹ anfaani rẹ lai si idiwọ.
Bakan naa lo dupẹ lọwọ igbimọ yii gẹgẹ bi wọn ṣe yan an fun ti aami ẹyẹ naa, to si loun yoo fi aami ẹyẹ ọhun sọri gbogbo ọmọ ipinlẹ Kwara jakejado.
Nigba ti wọn n gba ẹnu awọn igbimọ alakoso naa sọrọ, Olootu iwe iroyin naa lojoojumọ, Ọgbẹni Eze Anaba, ati Olootu opin ọsẹ, Ọgbẹni Onochie Anibeze sọ pe iwuri lo jẹ fawọn fun awọn ipa rere ti gomina naa ko, paapaa lẹka eto ẹkọ laaarin asiko to debẹ.
No comments:
Post a Comment