Oludije s'ipo gomina lẹgbẹ oṣelu PDP jade laye lojiji - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, January 25, 2023

Oludije s'ipo gomina lẹgbẹ oṣelu PDP jade laye lojiji


Oludije s'ipo gomina ipinlẹ Abia labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Ọjọgbọn Uchenna Ikonne ti jade laye, lẹyin aisan arampẹ.
 
Ikonne wa lara awọn to fẹẹ kopa nibi eto idibo gomina to fẹẹ waye lọjọ kọkanla, oṣu kẹta, ọdun 2023 ti a wa yii, gẹgẹ bi a ṣe gbọ, koda ti wọn ni ipalẹmọ naa ti lọ daadaa.
 
Ninu atẹjade ti ọmọ oloogbe naa, Chikezie fi sita lorukọ mọlẹbi, o jẹ ko di mimọ pe nnkan bi aago mẹrin aarọ oni, Ọjọru, Wẹsidee ni baba oun jade laye lẹyin aisan rampẹ.
 
Chikezie sọ pe aisan ọkan lo ti n ṣe baba oun tẹlẹ, to si ti lọ gba itọju l'ọsibitu kan lorileede United Kingdom. O nigba to pada de lo lọ sinmi ni ọsibitu kan nilyy Abuja, nibi to pada dakẹ si.
 
Bakan naa lo sọ pe lẹyin ti gbogbo mọlẹbi ba ti fẹnuko, awọn yoo kede bi eto isinku baba oun yoo ṣe lọ, to si dupẹ lọwọ gbogbo awọn aladuroti ati awọn ololufẹ baba oun, paapaa awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP fun ifẹ ti wọn ni.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI