Ẹ fi ọgba wa silẹ o - Ẹgbẹ akọroyin ṣe ikilọ f'awọn oloṣo, aṣẹwo ti wọn sọ ọgba wọn di ibiṣẹ oojọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 5, 2023

Ẹ fi ọgba wa silẹ o - Ẹgbẹ akọroyin ṣe ikilọ f'awọn oloṣo, aṣẹwo ti wọn sọ ọgba wọn di ibiṣẹ oojọ


Ọrọ buruku toun tẹrin nigba ti ẹgbẹ akọroyin, Nigeria Union of Journalist, NUJ, ẹka ti ipinlẹ Ogun ṣe ikilọ nla fun gbogbo awọn ọlọmọbinrin ti wọn ko n'iṣẹ meji ju iṣẹ aṣẹwo ati oloṣo lọ lati fi ọgba wọn silẹ lai fi akoko ṣofo.

Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe lati bi ọdun mẹrin si marun-un sẹyin ni oriṣiriṣi faaji aramanda ti n ṣẹlẹ ninu ọgba awọn akọroyin naa to wa ni Iwe-Irohin, Oke-Ilewo niluu Abẹokuta, nibi ti awọn ọlọmọge ti n lo anfaani rẹ lati ṣiṣẹ aṣẹwo.

Ninu atẹjade ti alaga ati akọwe tuntun ẹgbẹ naa ti wọn ṣẹṣẹ bura fun laipẹ yii, Kọmureedi Wale Ọlanrewaju ati Kọmureedi Bunmi Adigun fi ranṣẹ si AWIKONKO laaarọ oni, Ọjọbọ, Tọsidee, wọn ni awọn ko le laju silẹ mọ fun iwa adojutini naa.
 
Lati nnkan bi aago meje irọle, titi di oru ọjọ keji, ojoojumọ la gbọ pe faaji fi n ṣẹlẹ ninu ọgba awọn akọroyin naa, ti awọn eeyan yoo si maa ba ara wọn laṣepọ nita gbangba lai tiju.
 
Awọn iwa yii ni wọn sọ pe ko tẹ awọn oloye tuntun ẹgbẹ naa lọrun, ti wọn fi panupọ lati sọ pe awọn ko le gba iwa naa laaye mọ, ati pe ayipada rere ti de ba ẹgbẹ naa bayii.
 
Wọn ni o ṣeni laanu wi pe inu ọgba ileeṣẹ akọroyin to yẹ ko jẹ awokọṣe f'awọn araalu, ni awọn kan wa sọ di ile aṣẹwo ati oloṣo, ti onikaluku si n huwa to wuu, eyi ti wọn lawọn ko le gboju fo da mọ.

Bakan naa ni wọn tun fi ye wa pe awọn amookunṣeka tun n lo anfaani ti wọn fi gba awọn iwa buruku yii tẹlẹ lati maa ṣe ipade ikọkọ wọn nibẹ, ati pe opin ti de ba gbogbo iwa buruku naa lai fi akoko ṣofo.
 
Atẹjade naa sọ siwaju pe gbogbo awọn iwa adojutini to n ba orukọ ẹgbẹ akọroyin jẹ kaakiri igboro l'awọn ko nii gba laaye mọ, ti wọn si kilọ fun gbogbo awọn to n lọwọ si iwa ibajẹ naa lati dẹkun rẹ loju ẹsẹ.

Bẹẹ ni wọn jẹ ko di mimọ pe ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ nipa iwa aṣẹwo, oloṣo tabi oniruuru iwa adojutini ni wọn yoo foju winna ofin, nitori pe awọn ti fi to ileeṣẹ ọlọpaa at'awọn agbofinro, to fi mọ awọn oṣiṣẹ eleto aabo leti.
 
Siwaju sii ni wọn l'awọn ko tun ni gba mimu siga, egboogi oloro, ati ririn gberegbere layika ati inu ọgba wọn laaye mọ, nitori pe omi tuntun ti ru, iṣakoso to mọ ipa ti ẹgbẹ naa n ko ninu eto idagbasoke ilu ati orileede ti gbajọba.
 
"Iwe-Irohin kii ṣe agbegbe fun iṣẹ aṣewo ati oloṣo, tabi ọgba fun iwa ọdaran, bi ko ṣe ibi ti iwa ọmọluabi ti wulọ. A wa ti f'ẹnuko wi pe a nilo lati gba ileeṣẹ wa lọwọ awọn alailojuuti ati iwa aibofinmu ti awọn kan ti a ko mọ n hu. A si ti ṣetan lati jẹ ki gbogbo aye mọ pe ọgba wa kii ṣe ibi ti gbogbo eeyan le maa wa lati jokoo si, bi ko ṣe pe fun awọn to ba nilo iranlọwọ nipa igbese ofin."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI