Makinde ati PDP maa lulẹ lọdun yii - APC Ọyọ fọwọ sọya - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, January 4, 2023

Makinde ati PDP maa lulẹ lọdun yii - APC Ọyọ fọwọ sọya


Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), ẹka t'ipinlẹ Ọyọ ti sọrọ, wọn tun fọwọ sọya wi pe Gomina ipinlẹ naa, Onimọ-ẹrọ Ṣeyi Makinde ati ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) maa lulẹ n'ipinlẹ naa ninu eto idibo to n bọ l'oṣu kẹta ọdun yii.


Ninu atẹjade ti akọwe ipolongo ẹgbẹ APC nipinlẹ naa, Ọlawale Ṣadare gbe sita lọjọ Iṣẹgun, Tusidee ana, o ni gbogbo ọrọ ti PDP n gbe kaakiri ko lẹsẹ nilẹ rara.
 
O ni ọrọ ti ẹni to pe ara rẹ ni oloye oloye APC, Bashir Adeọla sọ lati fi takọ ẹgbẹ naa, ko le wa fi wa ojurere fun PDP ko lẹsẹ nilẹ rara, nitori pe ọrọ oṣelu ni.
 
Ṣadare, ni wọn ti ri gbogbo igbesẹ ti APC n gbe wi pe awọn yoo bori ninu eto idibo to n bọ lọna yii, lo n ba wọn leri, eyi lo mu ki wọn maa ṣe awawi kaakiri.
 
Bẹẹ lo sọ pe Bashiru Adeọla kii ṣe ọmọ ẹgbẹ APC rara.
 
“A ti farabalẹ wọ iwe orukọ awọn to jẹ ojulowo ọmọ ẹgbẹ oṣelu wa daadaa, a ko ri ẹni to n jẹ Bashiru Adeọla nibẹ. Ohun to n ya wa lẹnu ni bi awọn oniroyin PDP ti ri ẹni ti a ko mọ rara to n jẹ orukọ naa, lati gbẹnusọ fun APC.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI