Aarẹ Napoli ni ko si nnkan to le gbe Osimhen kuro ninu ẹgbẹ agbabọọlu wọn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, February 24, 2023

Aarẹ Napoli ni ko si nnkan to le gbe Osimhen kuro ninu ẹgbẹ agbabọọlu wọn


Aarẹ ilẹ Napoli, Aurelio De Laurentiis ti sọ pe oun nigbagbọ to yọranti ninu agbabọọlu ọwọ iwaju ọmọ orileede Naijiria nni, Victor Osimhen, to si ni yoo ṣi duro sinu ẹgbẹ agbabọọlu Napoli, ati pe ko si ibi to n lọ lasiko yii.
 
Ọrọ yii ko ṣẹyin bi awọon alaṣẹ ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ṣe lawọn n foju sọna lati gbe Osimhen wọnu ẹgbẹ agbabọọlu wọn laipẹ. 
 
Fawọn to ba mọ bi nnkan ṣe n lọ pẹlu Osimhen ni saa yii, ọmọkunrin naa ti gba bọọlu ogun wọle sawọn, bẹẹ lo tun ti ṣe iranlọwọ goolu mẹrin ọtọọtọ ninu ifarahan mẹrinlelogun rẹ.
 
Aarẹ ọhun, De Laurentiis sọ pe oun ṣi nigbagbọ ninu Osimhen, ati pe ko le jẹ iṣoro fun wọn lati maa san owo rẹ, fun idi eyi, o loun ko le buwọ lu lilọ rẹ kuro ninu ẹgbẹ agbabọọlu naa.
 
"Mo dara pupọ ninu ka tọwọ bọwe adehun, nitori naa nigba ti wọn wa ba mi, ko saaye fun wọn, fun idi eyi, gbigba wọn sibi ko le jẹ iṣoro fun wa.
 
"Sibẹsibẹ, ẹ ma ṣe sọ pe rara. Awọn anfaani miran wa ti ẹ ko le kọ, ẹ ko si le mọ iru ẹ."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI