APC ti n gbiyanju lati sun idibo yii siwaju - Atiku pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, February 24, 2023

APC ti n gbiyanju lati sun idibo yii siwaju - Atiku pariwo sita


Oludije s'ipo aarẹ orileede Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), Alaaji
Atiku Abubakar, ti fẹsun kan ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) wi pe wọn n gbiyanju lati da wahala silẹ lawọn ipinlẹ kọọkan.
 
Atiku ni gbogbo igbesẹ ti APC n gbe ni lati jẹ ki ajọ eleto idibo, Independent National Electoral Commission (INEC) sun idibo ọdun 2023 to fẹẹ waye lọjọ Abamẹta, Satide, ọla siwaju.
 
Bakan naa lo tun sọ pe niṣe ni wọn tun n ti ṣeto idibo ti ko nii fẹsẹ mulẹ, ti wọn yoo si ṣe atundi ibo lawọn ibi kan lorileede yii.
 
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ Atiku lori ọrọ iroyin, Phrank Shaibu fi sita lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee ana, o ni niṣe  ni APC n pe fun yiyi ibo niyẹn bi eto idibo ko ba le waye lẹẹkan ṣoṣo.
 
O ni “Wọn tun ti bẹrẹ pẹlu iwa jagidijagan wọn, gẹgẹ bi eyi ti wọn ṣe lọdun 2019. Wọn fi ipa mu atundi ibo, wọn si lo iwa ipa lati jawe olubori. A ti fidi rẹ mulẹ wi pe awọn nnkan wọnyi yoo waye nipinlẹ Borno, Yobe, Kaduna.
 
“Kaduna funra rẹ tun da yatọ ninu awọn ipinlẹ yii, nitori pr Gomina Nasir El-Rufai ti n sọ f'awọn eeyan rẹ lati ma ṣe tẹle ọrọ Aarẹ Muhammadu Buhari.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI