Ajalu nla tun kọlu ẹgbẹ oṣelu PDP ni Kwara, awọn agbaagba fẹgbẹ silẹ wọ APC lojiji - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, February 19, 2023

Ajalu nla tun kọlu ẹgbẹ oṣelu PDP ni Kwara, awọn agbaagba fẹgbẹ silẹ wọ APC lojiji


Ajalu nla lo tun de ba ẹgbẹ oṣelu People's Democratic Party (PDP), ẹka t'ipinlẹ Kwara pẹlu bi awọn agbaagba ati ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa ṣe lawọn ko le tẹsiwaju mọ, ti wọn si lawọn ti ba ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC lọ.
 
Gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ naa ti wọn wa labẹ akoso aarẹ ile igbimọ aṣofin agba tẹlẹri lorileede yii, Bukọla Saraki la gbọ pe wọn fẹgbẹ silẹ lojiji.
 
Awọn ọmọ ẹgbẹ naa lati ẹkun Ariwa ipinlẹ Kwara lawọn wọnyi ti wọn lawọn ti ba ẹgbẹ miran lọ lawọn ijọba ibilẹ Kosubosu ati Baruten. Ọjọ Ẹti, Furaidee to kọja ni gbogbo wọn fẹgbẹ silẹ lojiji.

Ohun to jẹ ki iroyin yii tun ya ọpọ eeyan lẹnu ni bo ṣe jẹ pe agbegbe naa ni oludije s'ipo gomina ipinlẹ naa labẹ asia PDP, Yaman Abdullahi ti jade.
 
Awọn to fẹgbẹ silẹ naa ni:
(1)Ahmed Mohammed
(2)Adamu Faruq
(3) Ibrahim Kabiru
(4)Musa Yaru Bello
(5) Ahmed Abubakar
(6)Adamu DAUDA
(7)YAHAYA Sherifudeen Salam
(8)Mora Hussein Lafia
(9)Abubakar Faruk
(10)Umar Idris
(11)Abubakar Umar 
(12) Abdulkareem Iliyas
(13)Ahmed Musimat Bekegi
(14) Mohammed Adamu
(15) Mohammed Hawawu
(16) Mohammed Fatimat
(17) Mohammed Zuliyat
(18) Umar Abdul wahab
(19) Sime Jafar
(20) Abdulkareem K. Abubakar
(21) Lafia Suleiman
(22) Adamu Abdulmutoleeb
(23) Aliyu Abubakar

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI