Ọdun marun-un lo ku fun mi lati maa fẹṣẹku-bi-ojo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, February 14, 2023

Ọdun marun-un lo ku fun mi lati maa fẹṣẹku-bi-ojo


Afẹṣẹku-bi-ojo ọmọ orileede Naijiria nni, Israel Adesanya to jẹ ẹni to mọ-ọn ja ju lagbaye tẹlẹ, iyẹn Former UFC Middleweight Champion, ti sọ pe ọdun marun-un si asiko yii loun yoo gbe akoto ija oun ti, toun yoo si fẹyinti.
 
Israel Adesanya lo sọrọ naa ṣaaju ifigagbaga ẹlẹẹkeji rẹ pẹlu Alex Pereira.
 
Bẹ o ba gbagbe, Adesanya to ti n di bẹliiti UFC mu tipẹtipẹ ni Pereira doju rẹ bolẹ lọdun to kọja, eyi ti yoo jẹ igbakẹta ti wọn yoo pade.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI