Ẹgbẹrun mẹjọ ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP fẹgbẹ silẹ, wọn ba APC lọ ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 9, 2023

Ẹgbẹrun mẹjọ ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP fẹgbẹ silẹ, wọn ba APC lọ ni Kwara


Ko din ni ẹgbẹrun mẹjọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu
People Democratic Party (PDP) ti wọn wa lagbegbe kan ti wọn n pe ni Bassa la gbọ pe wọn ti lọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC).
 
Gbogbo wọn la gbọ pe wọn sọ pe awọn ko le tẹsiwaju mọ lati maa ṣe ẹgbẹ ti ko ni ilọsiwaju ati afojusun rere f'awọn araalu.

Ọjọru, Wẹsidee la gbọ pe awọn eeyan naa kede sita gbangba wi pe b'awọn ṣe wa ninu ẹgbẹ PDP ko tẹ awọn lọrun, ṣugbọn ni bayii, awọn ti fi gbogbo ọkan wọn sinu ẹgbẹ PDP.
 
Nibẹ ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe awọn yoo gbaruku ti Gomina AbdulRaman AbdulRazaq lati pada s'ipo naa lẹẹkeji, nitori pe idagbasoke ati akanṣe iṣẹ to n ṣe lo mu ilọsiwaju ba ipinlẹ naa, laaarin ọdun mẹta ati oṣu bii mẹjọ to dori ipo naa.

Awọn ara Bassas nipinlẹ Kwara ni wọn wa lati awọn ipinlẹ bii Kogi, Nasarawa, Plateau, Niger, Benue, ati FCT, ti pupọ ninu wọn si jẹ agbẹ, to kaakiri ọpọ agbegbe n'ipinlẹ naa.

Ọba Aguma Abassa kinni, Daniel Shado Zhokwo la gbọ pe o lewaju awọn to lọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC naa lakoko ti wọn lọ fi erongba wọn han nile ẹgbẹ APC to wa niluu Ilọrin.
 
Amugbalẹgbẹ gomina lori ọrọ awọn ajoji, Ọnarebu Caleb Ono Bobi, ati igbakeji alaga APC, Alaaji Abdullahi Samari lo tẹwọ gba wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI