Alagbara ṣubu! Fadeyi Oloro ti ku oooooo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, March 8, 2023

Alagbara ṣubu! Fadeyi Oloro ti ku oooooo


Iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ bayii ti fidi rẹ mulẹ pe gbajugbaja oṣere tiata nnj, Ojo Arowoṣafẹ ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Fadeyi Oloro ti kade laye.

Fadeyi Oloro la gbọ pe o jade laye lẹyin bi ọdun mẹta to ti wa lori idubulẹ aisan.

Niṣe ni ariwo ibanujẹ sọ lori ayelujara lalẹ ana si oru mọjumọ oni, nigba ti iroyin ọhun jade sita wi pe Fadeyi Oloro ti pada gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra.

Fadeyi Oloro lo jade laye lọjọ Isẹgun lẹyin ti kidirin rẹ juwọ silẹ.

Iroyin sọ pe ọmọ rẹ fi aridaju eyi han fun awọn oniroyin bẹẹ si ni awọn akẹgbẹ rẹ naa ti bẹrẹ si ni fi sita lori ayelujara.

Ko to ku, Fadeyi Oloro rawọ ẹbẹ si awọn ọmọ orilẹede Naijiria pe ki wọn ran oun lọwọ lori ọro ti yoo fi ṣe itọju ara rẹ ni ile wosan.

Isẹlẹ yii waye lẹyin ọsẹ mẹta ti Pasitọ kan lati London, Tunde Adeboyega fun un ni miliọnu mẹta lẹyin ti o ṣalabapade fidio rẹ lori ayelujara.

Ṣaaju ko to ku, Fadeyi Oloro, ẹni to n mi gunle-gunle lati sọrọ sita ninu fidio kan, lo foju han pe o nira fun-un lati sọrọ ja soke.

O tẹsiwaju pe 
"Nigba ti aisan buruku naa de, n ko mọ nnkan to sẹlẹ, o kan dede ki mi ni, mo dẹ sare si, mo wo gbogbo agọ ara mi sugbọn gbogbo rẹ lo ye Ọlọrun.

"Mo ti kọ ọpọ awọn itan silẹ lati fi ṣe sinima sugbọn n ko le ṣe.

"Kekere ni ẹ pe aisan yii ni, to fi di pe wọn bẹrẹ si ni maa ta dukia lemi lori sugbọn gbogbo rẹ lo ye Ọlọrun."

1 comment:

  1. A ku ara fera ku o. Oruko Fadeyi kole parun lagbo tiata ni Nigeria laye laye. Ki Oluwa te Fadeyi Oloro si afefe rere.

    ReplyDelete

PÍN-IN KÁÀKIRI