Salakọ-Oyedele, igbakeji gomina ipinlẹ Ogun rawọ ẹbẹ sawọn Kristẹẹni lati dibo fun Dapọ Abiọdun lẹẹkeji - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, March 7, 2023

Salakọ-Oyedele, igbakeji gomina ipinlẹ Ogun rawọ ẹbẹ sawọn Kristẹẹni lati dibo fun Dapọ Abiọdun lẹẹkeji


Igbakeji gomina ipinlẹ Ogun, Onimọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ-Oyedele ti rawọ ẹbẹ s'awọn ẹgbẹ ọmọlẹyin Jesu to wa niluu Ọta lati dibo fun gomina ipinlẹ, Ọmọọba Dapọ Abiọdun lẹẹkeji, pẹlu ileri wi pe yoo ṣe daadaa ju saa akọkọ rẹ lọ.
 
Onimọ-ẹrọ Salakọ-Oyedele lo sọrọ naa lakoko to ṣabẹwo si ẹgbẹ ọmọlẹyin Jesu, bii Christian Association of Nigeria, CAN ati Pentecostal Fellowship of Nigeria, PFN, ẹka ti ilu Ọta l'opin ọsẹ to kọja yii, to si ni ki gbogbo wọn gbaruku ti gomina lọjọ Abamẹta, Satide to n bọ yii.
 
Nibi ipade naa to waye ninu ijọ Christian Penticostal Mission International (CPM), Animashaun niluu Ọta, lo ti sọ pe ọna kan ṣoṣo ti wọn le fi jẹ ki Dapọ Abiọdun pari awọn akanṣe iṣẹ to n lọ lọwọ ni lati jade lọpọ yanturu, ki wọn si dibo fun lẹẹkeji.
 
O tun ni, yatọ si Gomina Abiọdun, ki wọn tun dibo fun gbogbo awọn oludije s'ipo aṣofin ipinlẹ naa labẹ ẹgbẹ APC, ki itẹsiwaju le wa daadaa lai dawọ duro.
 No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI