Ayipada rere t'awọn eeyan n reti yoo bẹrẹ labẹ iṣakoso Tinubu - Wolii Iyunade ju asọtẹlẹ sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, March 8, 2023

Ayipada rere t'awọn eeyan n reti yoo bẹrẹ labẹ iṣakoso Tinubu - Wolii Iyunade ju asọtẹlẹ sita


Alaṣẹ ati oludasilẹ ijọ Pentecostal Sanctuary Bible Ministry to wa niluu Ikẹbu Ode, Wolii Sunday Dare Iyunade ti sọ pe ireti fawọn ọmọ orileede Naijiria nipa ayipada rere ti wọn n reti fun ọdun pipẹ, to si ni ayipada naa yoo bẹrẹ labẹ iṣakoso aarẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu.

Wolii Iyunade lo sọrọ naa nibi ipade awọn akọroyin to wa ninu ijọ rẹ to wa lagbegbe Odo Ẹgbọ, Ijẹbu Ode, nibẹ lo si ti sọ pe laaarin wakati mẹrinlelogun ti wọn ba bura fun Tinubu, awọn araalu yoo ni imọlara ayipada rere ọhun.

Siwaju sii ni agba Ojiṣẹ Ọlọrun naa sọ pe Aṣiwaju Tinubu gbọdọ gbọnran si awọn ọdọ lẹnu, to ba fẹ ilọsiwaju fun ijọba rẹ.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe
"Ọlọrun sọ fun mi pe ẹgbẹ oṣelu to n ṣakoso lọwọ ko tii ṣetan lati lọ, Ju gbogbo rẹ lọ, Ọlọrun fi da mi loju pe bi asiko wọn ba to, wọn yoo lọ. Mo wa n fi akoko yii rọ awọn araalu lati ṣe ọpọlọpọ suuru.

"Bi ijọba tuntun ṣe n bọ yii, ayipada rere ti gbogbo wa ti n beere fun yoo bẹrẹ lakoko iṣakoso yii.

"Eto oṣelu wa yoo lagbara sii, nitori pe ile igbimọ aṣofin wa ko nii jẹ eyi ti ẹgbẹ oṣelu kan ṣoṣo n ṣakoso rẹ. Ile igbimọ aṣofin naa yoo si rii pe nnkan lọ bo ṣe yẹ ko lọ.

"Bi wọn ba kọ lati ṣe ojuṣe wọn lọna to tọ, awọn ọdọ yoo dide lati le jẹ ki wọn ṣe ojuṣe wọn. Ti wọn ba si kọ, wọn maa paarọ wọn. Mo fẹẹ rọ aarẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan lati gbọ ohun ti awọn ọdọ ba n fẹ."

Ipade oniroyin ọhun lo waye lati fi bẹrẹ akanṣe eto idasilẹ ijọ naa to bẹrẹ lọsẹ yii, pẹlu alakalẹ eto loriṣiriṣi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI