Amosun gbe Ọtẹgbẹyẹ wọlu Ado-Odo Ọta fun ipolongo (Fọto) - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, March 4, 2023

Amosun gbe Ọtẹgbẹyẹ wọlu Ado-Odo Ọta fun ipolongo (Fọto)


Gomina ana n'ipinlẹ Ogun, Sẹnetọ Ibikunle Amosun ti gbe oludije s ipo gomina nipinlẹ naa labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Action Democratic Congress, ADC, Biyi Ọtẹgbẹyẹ wọ ilu Ado-Odo Ọta fun ipolongo idibo to n bọ lọna.
 
Sẹnetọ Amosun to n ṣoju ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ naa nile igbimọ aṣofin agba l'Abuja lo kọwọrin lati polongo ibo gomina to n bọ lọjọ kọkanla, oṣu kẹta, ọdun 2023 ti a wa yii.
 
Nibẹ lo ti fi da awọn ara agbegbe naa loju pe Ọtẹgbẹyẹ yoo daadaa fun wọn, ti yoo si jẹ ki wọn jẹ igbadun mudunmudun eto iṣejọba awaarawa.
 
Fọto


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI