Idajọ lori owo naira atijọ: Buhari gbọdọ tẹle idajọ ile-ẹjọ, bi bẹẹ kọ... - Oloye ẹgbẹ APC - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, March 4, 2023

Idajọ lori owo naira atijọ: Buhari gbọdọ tẹle idajọ ile-ẹjọ, bi bẹẹ kọ... - Oloye ẹgbẹ APC


Ọkan pataki lara awọn agba ẹgbẹ oṣelu All Progressives COngress, APC n'ipinlẹ Zamfara, Sani Abdullahi Shinkafi ti gba aarẹ Muhammadu Buhari lamọran lati tẹle idajọ ile ẹjọ agba lorileede yii, nipa owo naira atijọ.

Bẹ o ba gbagbe, ọjọ Ẹti, Furaide, ọsẹ yii ni ile ẹjọ agba orileede Naijiria, iyẹn Supreme Court paṣẹ pe ki awọn ọmọ Naijiria tẹsiwaju lati maa na owo atijọ lọ, titi di ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kejila, ọdun 2023.
 
Shinkafi, nigba to n b'awọn akọroyin sọrọ niluu Gusau sọ pe ki ipo to wa ma ṣe kun un lori, ko si ma ṣe ronu pe oun ga ju ofin orileede yii lọ.
 
“Niwọn igba ti ile ẹjọ agba ti paṣẹ, ko sẹni naa lorileede yii to le tapa si ofin ile ẹjọ.”
  
“Buhari ni lati tẹle aṣẹ ile ẹjọ, ko si paṣẹ fun ile ifowopamọ agba, Central Bank of Nigeria (CBN) lati da awọn owo naa pada sita lati maa na lọ”.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI