Awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ ni Kwara gba iwe igbega f'ọdun 2022 - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, March 12, 2023

Awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ ni Kwara gba iwe igbega f'ọdun 2022


Gbogbo awọn oṣiṣẹ ti wọn n ṣiṣẹ lawọn ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa n'ipinlẹ Kwara la gbọ pe wọn ti gba iwe igbega lẹnu iṣẹ wọn, eyi ti yoo mu koriya fun wọn.

Awọn ti a gbọ pe wọn tọ si igbega f'ọdun 2022 lawọn to gba iwe ẹri igbega naa, pẹlu idunnu ati ayọ ailopin.

Nigba to n kede sita, alaga ileeṣẹ to  ri sọrọ ijọba nipinlẹ Kwara, Alaaji Umar Danladi Shero, sọ pe Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lo bu ọwọo lu iwe igbega naa lai fi akoko ṣofo, pẹlu ileri wi pe oun yoo tubọ maa jẹ kọrọ awọn oṣiṣẹ jẹ oun logun.

Awọon oṣiṣẹ ti ko din ni ẹgbẹrun meji la gbọ pe wọn jẹ anfaani yii kaakiri ipo ti wọn wa lẹka iṣẹ ti wọn yan laayo, gẹgẹ bi alaga naa ṣe ṣalaye.

Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ wi pe Gomina AbdulRazaq ko da si ọrọ owo to n wọle sapo ijọba ibilẹ naa, to si ni bi ijọba ipinlẹ ṣe n ṣiṣẹ rẹ, naa ni ijọba ibilẹ n ṣe tiẹ, pẹlu owo oṣu ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira f'awọn oṣiṣẹ.

Siwaju sii lo sọ pe gbogbo ajẹẹlẹ t'awọn iṣakoso to ti kọja lọ ti jẹ silẹ, ni Gomina yii ti san patapata.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI