O ma ṣe o! Eefin jẹnẹretọ pa iya at'ọmọ danu l'Ondo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, March 12, 2023

O ma ṣe o! Eefin jẹnẹretọ pa iya at'ọmọ danu l'Ondo


Ariwo ikunlẹ abiyamọ lo gba ẹnu awọn ara agbegbe ilu Ọwọ, ipinlẹ Ondo lọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii, nigba ti wọn ba oku iya at'ọmọ, ti ọkọ ṣ wa ni baaku-baala.
 
Eefin to jade ninu ẹrọ amunawa ti jẹnẹretọ la gbọ pe o ṣeku pa iya at'ọmọ naa, gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe sọ.
 
Obinrin naa ti awọn eeyan mọ si Tawa, ati ọmọ rẹ, ọmọ oṣu marun-un ni wọn gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra.

AWIKONKO gbọ pe ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to ṣẹṣẹ n pari yii ni ọkọ Tawa wa jẹnẹretọ wa sile, lati le maa tan an nitori ooru to pọ lasiko yii, lai mọ pe jẹnẹretọ ọhun ni yoo pada fa ijamba fun wọn.
 
Wọn ni niṣe nni ọkunrin naa tan jẹnẹretọ yii, to si gbe e si eyin ferese ile to n gbe. Eefin naa la gbọ pe o wọnu ile wọn lati oju ferese, to si ṣeku pa wọn mọjumọ.
 
Ṣaaju asiko yii la gbọ pe Tawa pe ẹgbọn rẹ kan, iyẹn irọlẹ l'Ọjọbọ, Tọside, lati ṣalaye fun un wi pe ọmọ oun n ṣaisan, oun yoo si gbe e wa fun un toun ba ti de ibiṣẹ.
 
Ẹgbọn Tawa la gbọ pe ko gburo rẹ, idi ree to fi wa a lọ si ibiṣẹ, ti wọn si jẹ ko ye e pe ko wa sibiṣẹ lọjọ naa, ati pe awọn ko gburo rẹ.

Loju ẹsẹ ni wọn sọ pe obinrin naa, ati ọkan lara awọn to n ṣiṣẹ nileeṣẹ naa ti lọ wo o nile, to si jẹ iyalẹnu nigba to kan ilẹkun, ti ko si gburo ẹnikẹni lati da a lohun.

Ara to fuu lo jẹ ko ranṣẹ s'awọn to wa nitosi, ti wọn si pawọpọ lati ja ilẹkun ile naa wọle, to si jẹ iyalẹnu nigba ti wọn ba gbogbo wọn nilẹ, ti wọn ti fẹẹ ku.
 
Wọn ko fi ọrọ naa falẹ rara, ti wọn fi sare gbe wọn lọ si ọsibitu Federal Medical Centre to wa niluu Ọwọ lati doola ẹmi wọn, ibẹ si ni wọn sọ pe Tawa dakẹ si.
 
Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii tan, wọn ni baaku, baala ni ọkọ Tawa wa nibi to ti n gba itọju lọwọ. Ileeṣẹ ọlọpaa ni wọn ko tii sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI