Aye o! Awọn agbanipa yinbọn pa Babalọla 'Chicago', gbajumọ oniṣowo n'Ibadan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, March 12, 2023

Aye o! Awọn agbanipa yinbọn pa Babalọla 'Chicago', gbajumọ oniṣowo n'Ibadan


Ariwo Ikunlẹ abiyamọ lo gba ẹnu awọn ara agbegbe Agbariko to wa loju ọna Jemibewon, ijọba ibilẹ Ibadan North West, Ibadan, ipinlẹ Ọyọ nigba ti wọn l'awọn agbanipa yinbọn pa Ọgbẹni Ọladeji Babalọla, ẹni ti ọpọ awọn eeyan mọ si Chicago.

Ọsan ọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii la gbọ pe wọn pa Chicago danu, lakoko to n lọ sibi ti wọn ti pe e.

AWIKONKO gbọ pe odu ni Babalọla, ẹni ti awọn eeyan tun n pe ni Chicago, kii ṣaimọ foloko. Papa iṣere Lekan Salami to wa ni Adamasingba niluu Ibadan lo ti n ta awọn ohun elo ere idaraya bii bata, bọọlu, aṣọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe ṣọọbu ni Chicago wa, ti ẹnikan fi pe e lori foonu wi pe awọn fẹẹ ba a dowopọ, eyi lo jẹ ko sare wọ bata rẹ lati lọ sibẹ.

Wọn ni oju ọna lo wa ti awọn meji kan to wa lori ọkada fi n tẹle lẹyin. Bi wọn ṣe de agbegbe Onireke ni wọn yọ ibọn sii.

Ori ati aya la gbọ pe wọn ti yinbọn naa, ko to di pe wọn juba ehoro, ti ko si sẹni to le sọ bi wọn ṣe poora.

Awọn ọlọpaa la gbọ pe wọn wa gbe oku ọkunrin naa kuro nibi ti wọn pa a si, ti wọn si gbe e lọ si mọṣuari.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ Adewale Ọṣifẹsọ sọ pe otitọ ni, ati pe iwadii ti bẹrẹ lati mọ awọn to pa ọkunrin naa, to si lọwọ yoo tẹ gbogbo wọn laipẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI