Aye o! Gbajumọ pasitọ fipa ba iyale ile laṣepọ ninu ṣọọṣi l'Ondo, o tun luu pa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, March 25, 2023

Aye o! Gbajumọ pasitọ fipa ba iyale ile laṣepọ ninu ṣọọṣi l'Ondo, o tun luu pa


Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii lọrọ iku iyaale ile kan, Adejọkẹ Oloje ṣi n jẹ fun ọpọ awọn to gbọ nipa bo ṣe dagbere faye, paapaa awọn mọlẹbi ẹ, ṣugbọn ti ọwọ ti tẹ ẹnikan ti wọn pe ni pasitọ lori iṣẹlẹ naa.
 
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti f'idi rẹ mulẹ pe ọwọ awọn ti tẹ olori ijọ Oke Irapada to wa lagbegbe Alade niluu Idanre, ipinlẹ Ondo, Pasitọ Kayọde Salami lori iku obinrin naa, Adejọke.
 
AWIKONKO gbọ pe Adejọkẹ, ẹni to n tọmọ oṣu mọkanla lọwọ ni wọn sọ pe Pasitọ Salami fipa ba laṣepọ, to si tun luu pa, ki aṣiri rẹ ma ba a tu sita, bo tilẹ jẹ pe a ko le f'idi rẹ mulẹ.
 
Lara awọn to fi iṣẹlẹ naa to wa leti sọ pe Adejọkẹ lo lọ si ṣọọṣi naa pẹlu aburo rẹ kan, Aderonkẹ fun igba akọkọ, ni kete to de siluu Idanre l'oṣu kinni, ọdun yii lati ba wọn jọsin.
 
Wọn ni laipẹ yii ni Adejọkẹ kuro lọdọ mama rẹ, Arabinrin Deborah, to si gba ṣọọṣi naa lati lọ maa gbe, lai sọ pato ohun to gbe e debẹ.
 
Igba ti mama rẹ ko rii, lo bẹrẹ sii pe foonu ẹ, ṣugbọn ti ko gbe, eyi lo jẹ ko tubọ tẹsiwaju iwadii lati le mọ pato ibi to n gbe.
 
Ninu iwadii ti obinrin naa ṣe lo ti mọ pe ọdọ aburo rẹ, Aderonkẹ lo wa, to si pe e lati beere alaafia wọn, ṣugbọn tiyẹn sọ pe ṣọọṣi ni Adejọkẹ n gbe, eyi lo jẹ ko gba ṣọọṣi naa lọ.
 
Wọn ni bi mama naa ṣe de ṣọọṣi yii lo ti ri ọmọ rẹ, to si bẹ ẹ pe ko tẹle oun, ati pe ko kuro ni ṣọọṣi naa nitori to lewu fun un, ṣugbọn to loun ko le kuro ni ṣọọṣi naa.
 
Wọn ni Adejọkẹ sọ fun mama rẹ wi pe oun nilo ounjẹ ati owo, ti mama naa si loun yoo gbe e wa lọjọ keji fun. Igba ti mama naa yoo fi debẹ, o ṣeni laanu pe inu agbara ẹjẹ lo ti ba ọmọ rẹ.

Nigba to n sọrọ, mama naa sọ pe “Mo pe ẹrọ ibanisọrọ ọmọ mi titi lati mọ ibi to wa, ṣugbọn ko gbe e. Lọjọ kan ni mo wa ri awọn to sọ fun mi pe wọn rii lagbegbe Alade pẹlu ọmọ aburo mi, Aderonkẹ. Mo ni lati pe e, ṣugbọn to ni ṣọọṣi ni ọmọ mi wa.
 

Mo wa ọmọ mi de ṣọọṣi, mo si ba a. O loun nilo ounjẹ, mo si ni ma ba a gbe e wa, niwọn igba ti ko ti tẹle mi lọ sile. L'ọjọ keji, mo de ṣọọṣi naa ni nnkan bi aago marun-un irọlẹ, ọjọ keji.

“Bi mo ṣe debẹ, ni mo ti bẹrẹ sii gbohun ọmọ rẹ to n sunkun gidigidi. Mo ni lati sunmọ ibi ilẹkun lati mọ ohun to n ṣẹlẹ. O ya mi lẹnu pe oku ọmọ mi ni mo ba nilẹ pẹlu pata rẹ ti wọn ti bọ. Idi ree ti mo fi pariwo sita fun iranwọ.”
 
Mama naa lawọn eeyan lo ba oun gbe ọmọ oun lọ si ọsibitu, nibi ti wọn ti fidi rẹ mulẹ pe o ti ku. O ni loju ẹsẹ lawọn ti gba teṣan ọlọpaa lọ lati fi to wọn leti, ti wọn si lọ gbe e.

Ninu ọrọ Salami, o loun ko mọ nnkankan nipa iku Adejọkẹ, nitori pe oun ko si nile lasiko iṣẹlẹ naa, ati pe iranlọwọ lasan loun ṣe fun un nigba to wa ba oun.
 
“Aderonkẹ lo mu Adejọkẹ de ọdọ mi. Lẹyin yẹn lo pada wa wi pe oun fẹ maa gbe ninu ṣọọṣi, ki n foun laaye titi digba toun yoo fi ri owo lati gba ile.
 
“Mo ni lati fun un ni yara kan ninu yara to wa ni ṣọọṣi. Mi o beere nnkan to ṣẹlẹ sii, ki n to gbe igbesẹ naa. Gbogbo nnkan to le fi dana lo wa larọwọto. Ilẹkun kan lo wa laaarin yara ti mo n lo, ati yara toun naa n lo. Igba ti mo ba si fẹẹ jade tabi wọle ni mo maa n pe akiyesi rẹ sii, ko ma jẹ pe ihoho lo wa.
 
“A jọ ṣe iṣọ oru mọjumọ ọjọ yẹn ni. Mo si rii ki n to lọ si ibiṣẹ nitori pe iṣẹ wẹda ni mo n ṣe. Igba to di nnkan bi aago meji lo wa fi ina sinu foonu ẹ, to si pada wa mu laago mẹrin irọlẹ. Mi o mọ nnkankan nipa iku ẹ.

Ninu ọrọ agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa, Funmilayọ Ọdunlami, ṣalaye pe otitọ niṣẹlẹ naa, ṣugbọn Salami ti wa ni olu ileeṣẹ wọn, nibi ti wọn ti n fọrọ wa a lẹnu wo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI