Ekoo lawọn eleyii n gbe, ipinlẹ Ogun ni wọn ti n jale - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, March 25, 2023

Ekoo lawọn eleyii n gbe, ipinlẹ Ogun ni wọn ti n jale


Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ awọn ọrẹ mẹrin kan ti wọn ko niṣẹ meji ju idigunjale lọ, ti a si gbọ pe ipinlẹ Ekoo ni wọn fi ṣe ibugbe, ṣugbọn ipinlẹ Ogun ni wọn ti n digunjale ki aṣiri ma ba a tu.
 
Boroboro ni gbogbo wọn n ka nigba tọwọ ọlọpaa tẹ wọn lọjọ kẹtala, oṣu kẹta, ọdun ti a wa yii.
 
Agbegbe Ode-Rẹmọ, ijọba ibilẹ Ariwa Rẹmọ la gbọ pe wọn fẹran lati maa ṣiṣẹ idigunjale wọn, ṣugbọn ti ọwọ palaba wọn ti pada segi bayii.
 
Habeeb Salaudeen, ọmọ ọdun mẹrinlelogun; Ezekiel Jayesimi, ọmọ ọgbọn ọdun; Ọlamilekan Tẹniọla, ọmọ ọdun mejilelogun ati Ọlaitan Ṣọnibarẹ, toun jẹ ọmọ ọdun marundinlọgbọn lawọn mẹrẹẹrin tọwọ tẹ naa.
 
Abimbọla Oyeyẹmi to jẹ agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun nigba to n ṣalaye f'AWIKONKO, o ni ọwọ awọn ọlọpaa Ode-Rẹmọ lo tẹ wọn nigba ti wọn lọ digun ja ile kan to wa lagbegbe COTCO lole.
 
Wọn lawọn to wa lagbegbe naa ni wọn ranṣẹ s'awọn ọlọpaa, ti wọn fi lọ ko wọn.
 
Oyeyẹmi ni kete wọn ti foju kan ọlọpaa, ni wọn ti juba ehoro pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ Rav4 ti wọn gbe lọ, ṣugbọn ti awọn ọlọpaa da ibọn bo wọn.
 
Awọn ọlọpaa agbegbe Warewa ni wọn ṣakiyesi iho to jẹ ọta ibọn lara mọto wọn, ti wọn si da wọn duro. B'awọn ọlọpaa si ṣe da wọn duro, ni wọn ti fo bọ silẹ lati na papa bora.
 
Iwadii lo pada fidi rẹ mulẹ pe agbegbe Mushin nipinlẹ Ekoo ni wọn salọ.
 
Oyeyẹmi fi kun ọrọ rẹ pe awọn gba foonu iPhone mẹrin ọtọọtọ, foonu olowo nla mẹtala lọwọ wọn, ti wọn si tun ti jẹwọ.
 
Bakan naa lo ni wọn yoo foju ba ile ẹjọ laipẹ lẹyin ti iwadii ba tubọ pari, gẹgẹ bi ọga awọn Frank Mba ṣe paṣẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI