Aarẹ ati oludasilẹ ijọ Pentecostal Sanctuary Bible Ministry, Wolii Sunday Dare Iyunade ti sọ pe gbogbo awọn adari to ko orileede Naijiria sinu wahala ati idaamu ko nii lọ lai jiya ẹṣẹ wọn.
Wolii Iyunade lọ sọ asọtẹlẹ naa lakoko to n b'awọn akọroyin sọrọ ninu ijọ rẹ to wa niluu Ijẹbu Ode, ipinlẹ Ogun lonii, Ọjọru, Wẹsidee.
Nibẹ lo ti sọ pe gbogbo awọn to lọwọ si wahala, iṣoro ati idaamu t'awọn eeyan n koju yoo gba idajọ wọn, bẹẹ lo tun sọ pe ayipada rere yoo de ba eto aabo Naijiria labẹ iṣakoso tuntun.
Agba Wolii naa sọ pe ko tii to akoko tun atunto orileede Naijiria, iyẹn bi awọn eeyan ṣe n pe fun un, to si ni Naijiria yoo ṣi wa ni ọkan ṣoṣo.
"Ọlọrun tun fi n da mi loju, O si n tẹnu mọ-ọn fun mi pe gbogbo awọn to lọwọ si wahala t'awọn araalu n koju lasiko yii ko nii lọ lai jiya ẹṣẹ wọn.
"Ọlọrun tun sọ fun mi pe, akọsilẹ ijọba yii yoo tubọ maa ba nnkan jẹ sii ni. Eto aabo orileede yii yoo ni idagbasoke labẹ iṣakoso to n bọ. A nilo lati gbadura fun ipinnu rere.
"Ọlọrun sọ fun mi pe ko tii to asiko fun atunto orileede Naijiria pẹlu b'awọn eeyan ṣe n pariwo rẹ. Naijiria yoo duro gẹgẹ bi orileede kan ṣoṣo. Iṣọkan Naijiria jẹ Ọlọrun logun gidi lakoko yii.
"Ẹgbẹkẹgbẹ tabi ẹya to ba n pe fun pe ki Naijiria pin kan n ja ogun ti yoo padanu lasan ni."
No comments:
Post a Comment