Wọn ju baba arugbo sẹwọn gbere l'Ekoo, ọmọ ọrẹ rẹ, ọmọ ọdun mẹsan lo ja ibale rẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, March 25, 2023

Wọn ju baba arugbo sẹwọn gbere l'Ekoo, ọmọ ọrẹ rẹ, ọmọ ọdun mẹsan lo ja ibale rẹ


Ile ẹjọ to n gbọ ẹsun nipa ifipabanilopọ, iyẹn Sexual Offences and Domestic Violence Court n'ipinlẹ Ekoo ti ju baba agbalagba, ẹni ọdun mọkanlelaadọta kan, Ubregbo Parmer sẹwọn gbere pẹlu iṣẹ aṣekara n'ipinlẹ Ekoo.
 
Ọmọ ọdun mẹsan, to jẹ ọmọ alabaṣiṣẹpọ Parmer ni iroyin fi to wa leti pe o fipa ba laṣepọ karakara.
 
Onidajọ Abiọla Ṣọladoye to gbe idajọ naa kalẹ sọ pe ẹsun ti wọn fi kan Parmer fidi mulẹ gidi, nipa awọn ẹri ti ko ṣe e gboju fo da, to si lo gbọdọ jiya ẹṣẹ ẹ lẹkunrẹrẹ.
 
Siwaju sii ni Onidajọ Ṣọladoye sọ pe awọn ẹlẹrii ati ẹri ti dọkita fi kalẹ lori ẹsun ti wọn fi kan an lo jẹ ojulowo, ti wọn  ko si gbọdọ fọwọ bo idajọ ododo mọlẹ.
 
Bakan naa ni Onidajọ Ṣọladoye tun sọ pe wọn yoo kọ orukọ Parmer sinu iwe ọdaran awọn to n fipa banilopọ nipinlẹ Ekoo.
 
Onidajọ naa tun bu ẹnu atẹ lu mama ọmọ naa, lori aikiyesara pẹlu bo ṣe finu tan Parmer lati mu ọmọ rẹ lọ, lai si kii lọ yẹ ẹ wo loorekoore.
 
 
A gbọ pe iya ọmọ naa mu ọmọ rẹ lọ si ibiṣẹ lọjọ naa ni, iyẹn lọjọ kẹwaa, oṣu kejila, ọdun 2019, to si ni ki Parmer maa ba oun bojuto.
 
Wọn ni loju ẹsẹ ti iya ọmọ naa ti jade, ni Parmer ti sare bọ pata ọmọ yii, to si fipa ko ibasun fun un. Ọmọ naa lo ṣalaye fun mama rẹ, ko to di pe wọn lọ fa a le awọn ọlọpaa lọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI