Ẹkun egbere ni Peter Obi n sun lori tẹlifiṣan - Festus Keyamo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, March 4, 2023

Ẹkun egbere ni Peter Obi n sun lori tẹlifiṣan - Festus Keyamo


Agbẹnusọ fẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Festus Keyamo ti sọ pe ẹkun egbere ti ko lẹsẹ nilẹ lasan ni oludije s'ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour, Peter Obi n sun lori ẹrọ amohunmaworan laipẹ yii.

Keyamo ni itiju nla lo jẹ fun Obi, pẹlu bi awọn ọmọ ẹyin rẹ ṣe yi ibo un un nipinlẹ Eko ati ẹkun Guusu Ila-Oorun, to si tun pada lulẹ lẹyin ti wọn ka ibo tan.
 
Bẹ o ba gbagbe, Ọjọbọ, Tọsidee to kọja yii ni Obi pe ipade awọn oniroyin agbaye, nibi to ti tako bi ejọ INEC ṣe kede Bọla Tinubu gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu eto idibo apapọ ọdun 2023.
 
Ibi ipade naa ni Obi ti sunkun sita, to si ni ẹdun ọkan lo jẹ foun wi pe eto idibo naa ko ṣe oju rere foun.
 
Ẹ wo fidio ti Keyamo ti sọrọ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI