Ifẹoluwa to n fi ayederu fisa Canada lu awọn eeyan ni jibiti l'Abuja wọ gau - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, March 19, 2023

Ifẹoluwa to n fi ayederu fisa Canada lu awọn eeyan ni jibiti l'Abuja wọ gau


Ṣikun bayii lọwọ awọn oṣiṣẹ ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu kumọkumọ, iyẹn Economic and Financial Crimes Commission, EFCC, tẹ gendekunrin, ẹni ọdun mejilelọgbọn kan ti wọn sọ pe ko niṣẹ meji ju ko maa fi iwe irinna ti a mọ si Fisa lati maa fi lu awọn to fẹẹ rin irin ajo lọ soke okun ni jibiti.
 
A gbọ pe gbogbo awọn to ba n fẹ lati rin irin ajo lọ soke okun, yala lati lọ maa ṣiṣẹ, tabi lati lọ ka'we nibẹ ni wọn sọ pe gendekunrin naa, Enock Ifẹoluwa Ogungbamigbe maa n lu ni jibiti.
 
Oni, ọjọ Ẹti, Furaidee la gbọ pe ọwọ palaba Ifẹoluwa segi ni otẹẹli Transcorp to wa niluu Abuja.
 
A gbọ pe niṣe ni Ifẹoluwa gba miliọnu marun-un naira lọwọ ẹnikan, to si loun fẹ ba a ṣe fisa orileede Canada, ṣugbọn to jẹ pe jibiti lo lu ẹni naa.

Ẹni ọhun la gbọ pe o lọ fọrọ naa to awọn oṣiṣẹ ajọ EFCC leti, ti wọn fi bẹrẹ iwadii lori ẹ, ko to di pe ọwọ palaba ẹ segi.

Nigba tọwọ maa tẹ Ifẹoluwa, a gbọ pe niṣe lawọn oṣiṣẹ ajọ EFCC dọdẹ rẹ, wọn si pe e wi pe awọn ni iṣẹ kan lati gbe fun un, ati pe ko wa pade awọn ni otẹẹli Transcorp.

Loju ẹsẹ ni wọn loun naa ti gbera lọ sibẹ, lai mọ pe ibi ti ẹpa ko ti nii boro mọ foun ni. Wọn ni bo ṣe debẹ ni wọn ti gba a mu.
 
Ajọ EFCC nigba ti wọn n fidi iroyin ọhun mulẹ sọ pe Ifẹoluwa yoo foju ba ile ẹjọ laipẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI