Ọwọ Amọtẹkun tẹ ọrẹ meji to n digun jale l'Ọṣun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, March 17, 2023

Ọwọ Amọtẹkun tẹ ọrẹ meji to n digun jale l'Ọṣun


Ọwọ ẹṣọ aabo ilẹ Yoruba ti a mọ si Amọtẹkun, ẹka ti ipinlẹ Ọṣun ti tẹ awọn ọrẹ meji kan ti wọn sọ pe wọn ko niṣẹ meji ju idigunjale lọ, ti wọn si ti n ka boroboro.
 
Ṣẹgun Ajayi ati Sunday Adedọja lọwọ awọn ọrẹ meji naa tọwọ palaba wọn segi pẹlu ibọn ilewọ ẹlẹnu meji niluu Modakẹkẹ.

A gbọ pe awọn mejeeji yii ni wọn n da alaafia ilu Modakẹkẹ ati agbegbe rẹ laamu nipa iwa idigunjale wọn, ko to di pe okete wọn ko raaye boru.
 
Ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ni wọn pe Ajayi, nigba ti wọn sọ pe ẹni ọdun mẹtadinlogoji ni Adedọja.
 
Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ f'awọn akọroyin, ọga agba fun ileeṣẹ Amọtẹkun nipinlẹ Ọṣun, Benedict Akanni sọ pe ọwọ aarọ lọwọ tẹ awọn mejeeji l'ọjọ Iṣẹgun, Tusidee to kọja yii, lẹyin olobo to tẹ wọn lọwọ. 
 
O ni bawọn kan ṣe ta wọn lolobo, ni awọn ti bẹrẹ igbesẹ lati rọwọ to wọn, to si ni awọn gba ibọn ilewọ lọwọ wọn.
 
Bakan naa lo sọ pe awọn mejeeji yii ti lọ sẹwọn ri tẹlẹ, lori iwa ọdaran, ṣugbọn to ni wọn ko tun jawọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI