O pari! Daniẹli ta ọmọ rẹ, ọmọ oṣu mẹsan feeyan mẹta ọtọọtọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, March 17, 2023

O pari! Daniẹli ta ọmọ rẹ, ọmọ oṣu mẹsan feeyan mẹta ọtọọtọ


Ọrọ buruku toun tẹrin, pẹlu bi baale ile ẹni ọgbọ ọdun kan, Daniel Chigozie, ṣe ta ọmọ rẹ, ọmọ oṣu mẹsan an feeyan mẹta ọtọọtọ lagbegbe Ado-Odo Ọta, ipinlẹ Ogun.
 
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe adugbo Abẹla to wa ni Sango, ijọba ibilẹ Ado-Odo Ọta ni Daniel n gbe, nibẹ si lo ti ta ọmọ rẹ naa, Daniel Chinonye Darlington f'awọn eeyan.
 
A gbọ pe jibiti ni Daniel fi ọmọ naa lu awọn eeyan, paapaa awọn ti oju ọmọ n pọn.
 
Ọga agba ẹṣọ aabo Amọtẹkun nipinlẹ Ogun, David Akinrẹmi nigba to n ṣalaye bọwọ ṣe tẹ Danieli, o sọ pe ọkunrin naa ta ọmọ rẹ fun ẹnikan lagbegbe Sango, o tun ta a fẹlomiran lagbegbe Meiran ati agbegbe Apapa nipinlẹ Eko.

Wọn ni ẹgbẹrun lọna aadọjọ naira ni wọn sọ pe Daniel kọkọ ta ọmọ naa fun ẹnikan ni, ko to tun ta a ni ẹgbẹrun lọna irinwo naira fun ẹlomiran ni Meiran, ko to tun ta a ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin naira fun ẹnikẹta ni Apapa.
 
Aarin oṣu kẹjọ, ọdun 2022 si oṣu keji, ọdun 2023 la gbọ pe Daniel fi ọmọ rẹ yii lu jibiti naa, ko to di pe ọwọ palaba rẹ segi.

Wọn ni Daniel n ṣiṣẹ pẹlu awọn ajinigbe, to si mọ ọgbọn to fi n ji ọmọ naa gbe pada kuro lọwọ awọn to ba ta a fun, ko to di pe akara rẹ tu sepo lẹyin to ta a fun Ọmọwe Nosa niluu Apapa.

Akinrẹmi sọ pe Daniel ti jẹwọ f'awọn, t'awọn si ti fa a le ileeṣẹ to n ri sọrọ ijinigbe ati fifi ọmọ ṣoowo ẹru.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI