Ọsibitu ti gomina ipinlẹ Ogun ṣẹṣẹ ṣi lawọn eleyii lọ ji ẹru rẹ ko - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, March 17, 2023

Ọsibitu ti gomina ipinlẹ Ogun ṣẹṣẹ ṣi lawọn eleyii lọ ji ẹru rẹ ko


Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, ko tii daju pe awọn mẹta ti ẹ n wo yii yoo bọ ninu ẹsun idigunjale ti wọn fi kan wọn, ti wọn si tun ti jẹwọ pe lotitọ l'awọn n digunjalẹ.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ọsibitu igbalode ti ijọba ipinlẹ Ogun labẹ Gomina Dapọ Abiọdun ṣẹṣẹ kọ l'awọn mẹtẹẹta yii lọ fọ, ti wọn si ji awọn éru inu rẹ to to miliọnu mẹta naira ko.

Bo tilẹ jẹ pe kii ṣe ẹsun yii ni wọn kọkọ fi kan awọn mẹtẹẹta, ẹsun wi pe wọn lọ digun fọ ile ọkunrin kan to lọ si siluu Ekoo, ti wọn si ji awọn ẹru ile rẹ ko la gbọ pe wọn kọkọ fi kan wọn.
 
Wọn ni ẹnikan ti wọn pe orukọ rẹ ni Kẹhinde Banjoko lo lọ ṣalaye f'awọn ẹṣọ aabo Amọtẹkun wi pe awọn adigunjale ile oun lakoko toun lọ siluu Ekoo.

Kẹhinde sọ pe wọn ji jẹnẹretọ, ohun idana cylinder, faanu oniduro, ibusun, itẹlẹ ile ti a mọ si rọọgi, ati awọn nnkan miran ti owo gbogbo rẹ ko din ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira.

Iwadii lo pada f'idi rẹ mulẹ pe Ogunjẹmbọla Kẹhinde lo lewaju awọn to lọ digun fọ ile naa, ti wọn si ko awọn ẹru wọnyi salọ.
 
Ninu iwadii ni ọwọ ti tẹ Lawal Aliu, ẹni ti wọn loun lo n ra awọn ẹru naa lọwọ awọn adigunjale wọnyii.
 
Bi iwadii ṣe n tẹsiwaju ni iroyin ṣẹṣẹ tẹ awọn Amọtẹkun lọwọ pe Kẹhinde ni olori awọn to digun lọ fọ ọsibitu tijọba ipinlẹ Ogun ṣẹṣẹ ṣi lagbegbe Ipẹru, ijọba ibilẹ Ikẹnnẹ.
 
Igbakeji aarẹ orileede yii, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo lo fi ọsibitu to ni ọgọrun-bẹẹdi olutọju ninu
 
Lara awọn nnkan ti a gbọ pe wọn jigbe ni tẹlifiṣan Hisense mẹfa to jẹ 43-inch; tẹlifiṣan Bruhm meji to jẹ 65-inch; Firiiji Bruhm mẹta ọtọọtọ; firiiji nla Midea kan ati faanu Lontor mẹta ọọọtọ. Owo gbogbo awọn nnkan wọnyi ni wọn sọ pe ko din ni miliọnu mẹta naira.
 
David Akinrẹmi to jẹ ọga agba Amọtẹkun nigba to n sọrọ, o ni iwadii ṣi n lọwọ lati rii pe ọwọ tẹ awọn ọdaran yooku ti wọn jọ n ṣiṣẹ buruku yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI