Sẹnetọ Makanjuọla pada sẹgbẹ APC ni Kwara, o tun ni ko si nnkan to n jẹ ADC mọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, March 7, 2023

Sẹnetọ Makanjuọla pada sẹgbẹ APC ni Kwara, o tun ni ko si nnkan to n jẹ ADC mọ


Ọkan pataki lara awọon alẹnulọrọ n'ipinlẹ Kwara, Sẹnetọ Makanjuọla Ajadi ti kede sita gbangba wi pe oun ti pada s'inu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, ati pe ko si ija mọ laaarin oun atawọn alakoso ẹgbẹ naa.

Sẹnetọ Makanjuọla to wa lẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, ADC tẹlẹ, to si lawọn ọmọ ẹyin rẹpẹtẹ lo kede sita lakoko to ba Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ṣepade laipẹ yii niluu Ilọrin.

Nibẹ lo ti sọ pe gbogbo awọn oludije s'ipo ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa patapata labẹ asia ẹgbẹ oṣelu ADC ni wọn ṣetan lati juwọ silẹ fawọn oludije labẹ asia APC, ki itẹsiwaju le wa.
 
O ni lati le gba ifẹ ati alaafia laaye, ati pe bi wọn ba fẹ ki itẹsiwaju maa de ba ipinlẹ naa, a fi ki wọn fọwọsowọpọ, ki wọn si gbagbe ọrọ oṣelu to n dabaru nnkan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI