Ọwọ tẹ Abubakar mẹta lori ẹsun ijinigbe l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, March 17, 2023

Ọwọ tẹ Abubakar mẹta lori ẹsun ijinigbe l'Ogun


Ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ orileede yii,
Department of State Services, DSS ẹka ti ipinlẹ Ogun ti foju awọn mẹrin kan ba ile ẹjọ Majisireeti lori ẹsun iwa ọdaran ati dida alaafia agbagbe ilu laamu.

Ọjọru tii ṣe Wẹsidee to kọja yii la gbọ pe ajọ DSS foju awọn mẹrẹẹrin ba ile ẹjọ naa, niwaju Onidajọ M. O. Ọṣinbajo.
 
Awọn mẹrin naa: Aliu Abubakar, Abubakar Usman, Abubakar Amadu ati Adamu Aliu la gbọ pe ọwọ tẹ lọjọ kẹsan, oṣu kẹsan, ọdun 2022, ti wọn si foju wọn ba ile ẹjọ lọjọ kẹẹdogun, oṣu kẹta, lori ẹjọ ti nọmba rẹ jẹ MISC/15/2023, eyi to nii ṣe pẹlu ẹsun ọdaran ati ijinigbe.
 
Agbẹjọro DSS, Emmanuel Zamba, ninu ẹbẹ rẹ sọ pe ki ile ẹjọ ṣi paṣẹ wi pe k'awọn ọdaran naa wa lahamọ awọn titi digba ti igbẹjọ miran yoo tun waye, eyi ti ile ẹjọ naa gba wọle.
 
Onidajọ Ọṣinbajo ti wa sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹrin, ọdun yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI