Arujalẹ tiluu Okelusẹ l'Ondo wọlu Abẹokuta, o ṣabẹwo sawọn ọba Ẹgba ati Olumọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, April 14, 2023

Arujalẹ tiluu Okelusẹ l'Ondo wọlu Abẹokuta, o ṣabẹwo sawọn ọba Ẹgba ati Olumọ


Arujalẹ Ojima tiluu Okelusẹ to wa n’ijọba ibilẹ Ọsẹ, ipinlẹ Ondo, Ọba Oloyede Adeyẹọba Akinghare ll ti ṣabẹwo s’awọn ọba ilẹ Ẹgba niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.

Ọba Oloyede lo ṣabẹwo s’awọn ọba ilẹ Ẹgba, lojuna lati kẹkọọ siwaju sii nipa ipo ọba, ati igbe aye ọba, ati lati ni ibaṣepọ to dan mọnran pẹlu awọn ọba ilẹ Yoruba kaakiri.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ilẹ Ọba tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan niluu Orile-Ilawọ, Ọba Oluṣẹgun Alexandar Macgregor to wa niluu Abẹokuta ni Ọba Oloyede de si, ko to di pe wọn lọ kaakiri lati b’awọn ọba ilu Ẹgba lalejo.

Lara awọn to fi iroyin naa to wa leti sọ pe ṣaaju akoko yii ni aajọṣepọ to dan mọnran ti wa laaarin Ọba Oloyede ati Ọba Macgregor, eyi to jẹ ki wiwa rẹ sipinlẹ Ogun lọ nirọrun.


AWIKONKO gbọ pe lara awọn ọba ti kabiyesi naa ṣabẹwo si ni Alake tilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ; Agura tiluu Gbagura, Ọba Babajide Bakre; Olowu tilu Owu, Ọba Saka Matẹmilọla; to fi mọ Ọṣilẹ Oke-Ọna Ẹgba, Ọba Adedapọ Tẹjuoṣo.

Olori awọn oṣiṣẹ Ọba Adeyẹọba, Ọmọọba Oluwafẹmi to kọwọrin pẹlu kabiyesi nigba to n gba ẹnu rẹ sọrọ sọ pe o ti pẹ t’awọn ti n gburo nipa ilu Ẹgba, to si ti wa lọkan awọn lati wa, ati pe kii ṣe lati ṣabẹwo siluu Ẹgba nikan, bi ko ṣe lati ni ibaṣepọ to dan mọnran papọ pẹlu awọn ori ade to wa nibẹ.

Kabiyesi naa ni inu oun dun pupọ nigba toun de siluu Ẹgba, toun si ri bi ibẹ ṣe rẹwa to, ati pe o yatọ si oju t’awọn fi n ka a itan naa ninu iwe ati lori ẹrọ ayelujara.

Bakan naa lo sọ pe oun dupẹ lọwọ awọn ọba alaye naa ti wọn tẹwọ gba oun pẹlu ifẹ ati alaafia, to si ni bo ṣe yẹ ki nnkan ṣe ri kaakiri orileede Naijiria lapapọ niyẹn.

Awọn ọba ilẹ Ẹgba ninu ọrọ wọn gba kabiyesi naa lamọran, bẹẹ ni wọn jẹ ko di mimọ pe ipo ẹlẹgẹ ni ipo ọba jẹ, nitori pe ko le faaye silẹ lati ṣe awọn nnkan to ba wu eeyan, nitori naa, o ni ki ọba yii.

Wọn ni igbagbọ awọn ni pe Ọlọrun yoo tubọ maa fun un ni ọgbọn, imọ ati oye lati dari awọn araalu, ati pe koun naa maa gba ifẹ, iṣọkan ati alaafia laaye laarin awọn eeyan rẹ nigba gbogbo.

Bẹẹ ni wọn sọ pe gbogbo ohun to ba ti nii ṣe pẹlu idagbasoke ni ki kabiyesi naa maa wa f’awọn eeyan ilu ẹ, ki idagbasoke ati ilọsiwaju le da ba ilu to j’ọba si, nitori pe ọba to jẹ tiluu toro, orukọ rẹ ko le parẹ lailai.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI