Awọn adigunjale wọlu Abẹokuta, wọn pa eeyan kan danu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, April 14, 2023

Awọn adigunjale wọlu Abẹokuta, wọn pa eeyan kan danu


Niṣe lọrọ di boolọ o yago lọna nigba ti wọn lawọn adigunjale ti ko din ni mẹjọ yawọ agbegbe ti wọn ti n ta foonu, iyẹ Tarmac to wa niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun l'Ọjọru, Wẹsidee, ọsẹ yii.
 
Ohun ti a gbọ ni pe nnkan bi aago marun-un aabọ irọlẹ, lakoko ti karakata ṣi n lọ lọwọ lawọn adigunjalẹ naa yawọ gbagede ile itaja foonu ọhun, ti wọn si gba ọpọ dukia salọ.
 
Gẹgẹ bi a gbọ, wọn ni bawọn adigunjale naa ṣe wọnu ọgba yii ni wọn ti dabọn bolẹ, eyi to mu k'awọn to wa nitosi juba ehoro, ti olori si di ori ara rẹ mu.
 
Awọn kan ti ẹ kọkọ ro pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ni wọn doju ija kọ ara wọn, ṣugbọn nigba ti wọn woye daadaa, ni wọn ṣakiyesi adigunjale ni wọn, eyi lo jẹ k'awọn naa dide lati koju wọn.

Ibi ti wọn ti koju wọn la gbọ pe ibọn t'awọn adigunjale naa yin ti lọ ba ẹnikan ti wọn pe orukọ rẹ ni Dayọ Bankọle, ẹni ti wọn lo pada gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra lọsibitu.
 
Abimbọla Oyeyẹmi to jẹ agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun ninu ọrọ rẹ sọ pe awọn t'awọn adigunjale naa lọ ka mọ rọwọ to ọkan lara wọn, ti wọn si ti fa a le awọn lọwọ.
 
O ni Adeniji Ṣakiru, ẹni ọdun mejilelọgbọn lọwọ tẹ pẹlu ibọn ilewọ ti wọn gba lọwọ ẹ.
 
Oyeyẹmi sọ pe Ṣakiru ti wa nibi ti wọn ti n fọrọ wa a lẹnu wo lọwọ lagọ wọn, to si ni ọga awọn, Frank Mba ti paṣẹ pe ọwọ gbọdọ tẹ awọn yooku to na papa bora lati foju wọn jofin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI