Ekoo ni Muyiwa ati Lukman n gbe, Ijẹbu-Ode ni wọn ti n digunjale - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, April 12, 2023

Ekoo ni Muyiwa ati Lukman n gbe, Ijẹbu-Ode ni wọn ti n digunjale


Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ awọn ọrẹ meji kan ti a gbọ pe wọn ko niṣẹ meji ju iṣẹ adigunjale lọ, ti wọn si ni ogbologbo ni wọn ninu iṣẹ idigunjale.
 
Muyiwa Adebọla ati Lukman Ogunmuyiwa lorukọ awọn mejeeji ti a gbọ pe ọwọ palaba wọn segi. Ilu Ijẹbu-Ode ati agbegbe rẹ, la gbọ pe wọn fẹran lati maa ṣiṣẹ buruku wọn, ko to di pe akara wọn tu sepo.
 
Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹta, ọdun ti a wa yii lawọn ọlọpaa sọ pe ọwọ tẹ awọn mejeeji.
 
Abimbọla Oyeyẹmi nigba to n fidi rẹ mulẹ laipẹ yii, ṣalaye pe awọn ọlọpaa ẹkun Igbẹgba nitosi Ijẹbu-Ode lo rọwọ to wọn nigba ti olobo ta wọn.
 
O ni mẹfa lawọn adigunjale naa ti wọn lọ digun ja awọn ara agbegbe Imoru Ijẹbu ni nnkan bi aago kan aabọ oru, ti wọn si gba ọpọ dukia ati owo.
 
AWIKONKO gbọ pe lara awọn ẹru ti wọn gba ni foonu oriṣiriṣi mejilelọgbọn, mọto ayọkẹlẹ GLK Mercedes Benz to ni nọmba idanimọ KRD 570 HM.
 
Nibi ikọlu naa la gbọ pe wọn ti yinbọn fun Ayọọla Taiwo, ẹni ti wọn lo wa lọsibitu, nibi to ti n gba itọju
 
Oyeyẹmi tẹsiwaju pe awọn ara agbegbe naa ni wọn ranṣẹ s'awọn ọlọpaa fun iranlọwọ aabo, ti awọn naa fi sare gbera lọ sibẹ.

Loju ẹsẹ ti wọn lawọn adigunjale yii ti gburo pe awọn ọlọpaa ti wa nitosi lati doju ija kọ wọn, ni wọn ti na papa bora, ṣugbọn ti awọn ọlọpaa naa tẹle wọn.
 
Ọkan ninu wọn lọwọ pada tẹ, iyẹn Muyiwa Adebọla lagbegbe Olisa niluu Ijẹbu-Ode, ti wọn si gba ọkan lara awọn foonu ti wọn jigbe lọwọ wọn.

Muyiwa lo pada jẹwọ pe ilu Ekoo lawọn n gbe, ibẹ si lawọn ti maa n wa si Ijẹbu-Ode lati jale, ki aṣiri ma ba a tu. Oun lo si mu awọn ọlọpaa lọ si agbegbe Mushin, nibi ti ọwọ ti tẹ Lukman Ogunmuyiwa, ẹni toun naa tun jẹwọ pe lotitọ ni.
 
Lara nnkan ti wọn tun gba lọwọ wọn ni ẹrọ kọmputa alagbeka mẹta ati foonu mẹta, eyi ti wọn jigbe.
 
Ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun to ti n lọ, Frank Mba ti wa paṣẹ pe ki iwadii tubọ tẹsiwaju lati rii pe ọwọ tẹ awọn yooku.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI