Iwadii bẹrẹ lori gbajumọ oniṣowo ori ayelujara ti wọn ba oku rẹ l'otẹẹli n'Ibadan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, April 12, 2023

Iwadii bẹrẹ lori gbajumọ oniṣowo ori ayelujara ti wọn ba oku rẹ l'otẹẹli n'Ibadan


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti sọ pe awọn ti bẹrẹ iwadii lẹkunrẹrẹ lori gbajugbaja oniṣowo ori ayelujara nni, Adeshina Ọlayinka, ẹni ti wọn sọ pe wọn ba oku rẹ ni otẹẹli kan niluu Ibadan laipẹ yii.
 
Ọlayinka, ẹni tọpọ awọn eeyan tun mọ si Khadi la gbọ pe o lọ ba ọkan lara awọn onibara rẹ ni otẹẹli Wetland to wa lagbegbe Akobọ.
 
Lẹyin toun pẹlu onibara rẹ naa to jẹ ọkunrin dunadura tan, la gbọ pe Khadi ṣi duro si otẹẹli naa lati fun ara rẹ ni isinmi.

Igba ti wọn ni asiko to lati jade ni wọn lọ lati sọ fun un, ṣugbọn to jẹ kayeefi pe oku rẹ ni wọn ba ninu yara otẹẹli naa.

Ṣaaju asiko yii, wọn ni Khadi ti sọ fun ọrẹ rẹ kan wi pe oun fẹ lọ pade ọkan lara awọn onibara oun ni otẹẹli lalẹ Ọjọru, Wẹsidee, ṣugbọn to pada jẹ pe iroyin iku rẹ ni wọn pada gbọ.

Koda, igba ti wọn sọ pe ẹni ti Khadi lọ ba ni otẹẹli naa fẹẹ jade lati maa lọ, wọn ni awọn oṣiṣẹ ibẹ gbiyanju lati pe Khadi, iyẹn lati mọ boya alaafia lo wa, to si da wọn lohun pe alaafia ni, ati pe oun fẹẹ sinmi diẹ ko to di pe oun maa lọ sile ni, iyẹn laaarọ ọjọ keji, to jẹ Tọsidee.
 
Nigba ti iroyin iku Khadi jade, wọn ni awọn oṣiṣẹ otẹẹli naa sare pe ọkunrin ti wọn jọ wa lati fi to o leti, ti wọn si sọ pe loju ẹsẹ ni ọkunrin naa ti debẹ lati mọ nnkan to n ṣẹlẹ.
 
Ọkunrin ọhun ni wọn sọ pe o ṣi wa lagọ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, nibi ti wọn ti n fọrọ wa a lẹnu wo lọwọ.



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI