Iwadii bẹrẹ lori iku Kabirat ti wọn dumbu bi ẹran l'Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, April 6, 2023

Iwadii bẹrẹ lori iku Kabirat ti wọn dumbu bi ẹran l'Abẹokuta


Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii lọrọ iku ọdọmọbinrin, ọmọ ọdun mejilelogun kan, Kabirat Ṣobọla ṣi n jẹ fun ọpọ awọn to gbọ, paapaa awọn obi rẹ, ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun si ti jẹ ko di mimọ pe iwadii ti bẹrẹ lẹkunrẹrẹ.
 
Kabirat, ti wọn lo ṣẹṣẹ pari ipele akọkọ ẹkọ, ND rẹ nile ẹkọ gbogboniṣe ti Mọshood Abiọla to wa niluu Abẹokuta la gbọ pe awọn amookunṣeka pa danu sinu ile to n gbe lagbegbe Adigbẹ, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja.
 
Gẹgẹ bi AWIKONKO ṣe gbọ,  niṣe ni wọn dumbu Kabirat, ti wọn si tun fi ọbẹ gun un ni ọkan, titi to fi jade laye.
 
Ọkan lara awọn mọlẹbi oloogbe naa, Arabinrin Ṣobọla nigba to n sọrọ tun fẹsun kan awọn ọlọpaa wi pe wọn fẹ maa gbabọde lori iṣẹlẹ naa, ati pe wọno ti bẹrẹ sii fiya jẹ alaiṣẹ.
 
Ṣobọla sọ pe ko si idi kan ni pato ti awọn ọlọpaa fi maa fẹsun kan ololufẹ Kabirat wi pe oun lo pa a. O ni ololufẹ Kabirat lo lọ ta awọn ọlọpaa lolobo wi pe awọn n wa a.

Ninu ọrọ rẹ, “Ori bẹẹdi lati ba oku Kabirat pẹlu ọbẹ lẹgbẹẹ, a ri ọgbẹ nla ni ọrun ati aya rẹ. A ko ri foonu ẹ, awọn ọlọpaa ti fi ẹtẹ silẹ, lapalapa ni wọn n le lati pa bayii. Wọn ko sọrọ foonu Kabirat ninu ọrọ wọn.
 
“Nigba ti a ko rii, ololufẹ rẹ lo lọ si teṣan ọlọpaa lati lọ fi to wọn leti lọjọ kẹta, oṣu kẹta, ọdun yii. Gẹgẹ bi DPO ṣe sọ, o ni ori kanta ni ololufẹ naa ti pade oun, to si ni ẹni t'awọn fura si niyẹn, nitori pe ko tii to wakati mẹrinlelogun ki wọn to wa fi to wọn leti.
 
O ni titi lawọn ba ilẹkun, nigba t'awọn lọ sile ẹ lati wo o, ṣugbọn iwadii awọn ọlọpaa lo fi han pe inu ile ni ọmọbinrin naa wa, ko to di pe wọn ja ilẹkun.
 
Abimbọla Ọyẹyẹmi, nigba toun naa n sọrọ, ṣalaye pe iwadii ti bẹrẹ lati mọ awọn to pa Kabirat, to si ni ololufẹ naa ti wa lahamọ awọn ni Eleweran lati fọrọ wa a lẹnu wo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI