Awọn marun-un dero atimọle l'Ekoo nitori iku ọlọpaa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, May 6, 2023

Awọn marun-un dero atimọle l'Ekoo nitori iku ọlọpaa


Eeyan marun-un la gbọ pe wọn ti dero atimọle ọlọpaa ipinlẹ Ekoo bayii nitori iku ọlọpaa kan ti a gbọ pe wọn ṣeku pa, koda ti wọn tun ti foju ba ile-ẹjọ.
 
Ọjọ Ẹti tii ṣe Furaidee, ọsẹ yii la gbọ pe awọn maraarun-un foju ba ile ẹjọ Majisireeti to wa lagbegbe Sabo Yaba nipinlẹ Ekoo, nibi ti onidajọ ti sọ pe ki wọn ṣi lọ maa gbatẹgun lahaamọ ọlọpaa titi igbẹjọ miran yoo fi waye.
 
Ṣhakiru Shittu, ẹni ọdun mejidinlaadọta; Kadir Shonọki, ẹni ọdun mejidinlogoji; Shadiku Adeọla, ẹni ọdun mẹtalelogoji; Taofeek Aluko, ẹni ọdun mejidinlogoji ati Adekunle Ọnasanya, toun jẹ ẹni ọdun mẹtadinlogoji la gbọ pe wọn fẹsun meji ọtọọtọ kan to niiṣe pẹlu ipaniyan kan.

Onidajọ Peter Nwaka, to kọ lati gba ẹbẹ awọn maraarun-un paṣẹ pe ki wọn gbe iwe ẹsun naa lọ sọdọ alakoso eto ilanilọyẹ ijẹjọ, iyẹn Director of Public Prosecutions fun igbaninimọran.
 
Bẹẹ lo sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu karun-un, ọdun ti a wa yii.

Agbefọba to fẹsun kan awọn eeyan naa niwaju ile ẹjọ, Ọgbẹni Good Friday, ṣalaye pe ọjọ kẹfa, oṣu kẹrin ọdun ti a wa yii ni wọn tapa si ofin ni ikorita Emurẹn to wa niluu Ikorodu, ipinlẹ Ekoo.
 
O ni ọlọpaa kan to n jẹ ASP Mathew Aniaguru, ni wọn ṣeku pa lẹnu iṣẹ rẹ lọjọ naa, ti wọn si salọ, ṣugbọn ti ọwọ pada tẹ wọn.
 
Nibẹ lo ti sọ pe niṣe lawọn tọọgi kan kọlu awọn ọlọpaa ni ikorita Emurẹn naa, ti wọn si lu wọn lalubami, nibi ti wọn ti yinbọn pa Mathew
 
AWIKONKO gbọ pe ọkan lara awọn ọlọpaa ti wọn jọ lọ, ASP Adamu Audu lo ranṣẹ pe awọn ọlọpaa to wa nitosi wi pe awọn tọọgi kọlu awọn nikorita Emurẹn, ti wọn si lawọn yẹn naa gbera lati lọ wo nnkan to n ṣẹlẹ.

Bi wọn ṣe debẹ la gbọ pe awọn tọọgi gba ibọn AK-47 to ni ọta ibọn mẹwaa ninu, eyi ti Mathew gbe dani, ti wọn si yinbọn naa fun un.
 
Lẹyin rẹ la gbọ pe awọn ọlọpaa gbana jẹ, ti wọn si pada ṣa awọn eeyan lagbegbe naa, ko to di pe wọn foju wọn ba ile ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI