Poosi, oogun abẹnugọngọ, igba atawọn nnkan miran ni wọn gba lọwọ ogoji ọmọ 'Yahoo-Yahoo tọwọ tẹ l'Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, May 6, 2023

Poosi, oogun abẹnugọngọ, igba atawọn nnkan miran ni wọn gba lọwọ ogoji ọmọ 'Yahoo-Yahoo tọwọ tẹ l'Abẹokuta


Ko din ni ogoji gendekunrin ti a gbọ pe wọn ko niṣe meji ju jibiti ori ayelujara, eyi ti a mọ si 'Yahoo-Yahoo' lọ, tọwọ ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede yii, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), ẹka tiluu Ibadan n'ipinlẹ Ọyọ tẹ niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.
 
Ninu atẹjade ti ajọ EFCC gbe jade l'Ọjọbọ tii ṣe Tọsidee, ọsẹ yii la gbọ pe Ọjọru tii ṣe Wẹsidee lọwọ tẹ gbogbo wọn kaakiri igboro ilu Abẹokuta ati agbegbe rẹ.
 
Wọn ni ẹka ajọ naa to wa niluu Ibadan lo rọwọ to wọn lẹyin olobo to ta wọn, eyi to mu ki wọn bẹrẹ iṣẹ iwadii lori wọn.
 
Lara awọn nnkan ti wọn gba lọwọ  wọn ni poosi, oogun abẹnugọngọ, igba, mọtọ bọginni meje, kọmputa alagbeka, foonu olowo nla loriṣiriṣi, aago olowo nla Apple at'awọn nnkan miran.
 
Ninu awọn tọwọ tẹ ni; Emmanuel Adebọwale Oluwọle, Jaiyeọba Daniel Ọlamilekan, Ọdunjọ Sọdiq, Ọmọdele Peter Idowu, Aligamhe John Clement, Kounchi Sunday Damilare, Ojo Abdul Quadri Adewale, Ọlamilekan Ọlamide Danusi, Nafiu Waris Ayọmide, Sọdiq Ọpẹyẹmi Sunday.
 
Awọn miran ni; Gbenga Akinwunmi, Ọdunnbaku Isikilu Ọlawale, Akinpẹlu Quadri Ọpẹyẹmi, Idris Gbọlahan Abdulazeez, Akintaro Isaac Oluwabumiṣe, Bamgbade Clement, Adebọwale Adejare Abdulsalam, Aliu Damilọla Daramọla, Ọlaitan Gbenga Josiah ati Dosumu Michael Ayọmide.
 
Lara awọn yooku ni; Faruq Azeez Ọlanrewaju, Ọlaoluwa Daniel, Ṣiyanbade Timilẹhin, Ọlaiya Nifẹmi Samuel, Rasak Abdullahi Adeṣhina, Owolabi Mustapha Ayọmide, Ọlọlade Sunday Ọlamide, Elegbede Mọruf Ọlamilekan, Ọlanrewaju Ọlamilekan Ṣeun, Tobilọba Alayọ Lekan, Damilọla Sunday Ṣhowunmi, Shittu Waheed Adeleke, Ọlanrewaju Adeoye, Adeniyi Gbọlahan Ọlamilekan, Theophilus Onoapor, Lawal Usman, Ṣogbaike Boluwatifẹ Martins, Raji Ẹniọla Al-Hamin, Adelẹyẹ Damilọla Testimony ati Ọlaniyan Daniel Ayọdeji.

Ajọ EFCC ti jẹ ko di mimọ pe awọn yoo foju gbogbo wọn ba ile ẹjọ lẹyin ti iwadii ba tubọ pari, ati pe pupọ ninu wọn lo ti n jẹwọ fun wọn.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI