Ẹran igbẹ ni Wakili ati Biọdun fẹẹ pa, lo ba yinbọn fun Sikiru l'Ọṣun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, May 6, 2023

Ẹran igbẹ ni Wakili ati Biọdun fẹẹ pa, lo ba yinbọn fun Sikiru l'Ọṣun


Ọwọ ileeṣẹ eleto aabo ilẹ Yoruba ti a mọ si Amọtẹkun ti tẹ awọn meji kan nipinlẹ Ọṣun, Nafiu Biọdun, ọmọ ọdun mọkanlelogun ati Tijani Wakili Dada, ọmọ ọgbọn ọdun lori ẹsun igbiyanju lati ṣeku paayan.


Ẹnikan ti wọn pe orukọ rẹ ni Lateef Sikiru, la gbọ pe awọn mejeeji fẹẹ ṣeku pa lagbegbe Apomu, ijọba ibilẹ Iṣọkan, ipinlẹ naa.

Ọjọru, Wẹside, ọsẹ yii la gbọ pe awọn kan lọ fi to ileeṣẹ Amọtẹkun to wa lagboole Iṣọkan leti, ti wọn si bẹrẹ iṣẹ iwadii wọn loju ẹsẹ. Ko pẹ rara ti wọn lọwọ fi tẹ awọn mejeeji.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ f'awọn akọroyin niluu Oṣogbo, ọga agba Amọtẹkun, Ajagunfẹyinti Bashir Adewinmbi ṣalaye [pe agbegbe meji ọtọọtọ lọwọ ti tẹ wọn.
 
Adewinmbi fi ye wa pe niṣe ni wọn yinbọn fun Sikiru. O ni Biọdun jẹwọ pe lootọ loun yinbọn fun Sikiru. Bẹẹ ni Wakili sọ pe oun gbe ibọn fun Biọdun, nigba to sọ foun pe oun fẹẹ pa ẹran igbẹ, lai mọ pe eeyan lo yinbọn fun.

Ọga agba naa fi ye wa pe awọn ti fa awọn mejeeji le awọn ọlọpaa lọwọ lati tẹsiwaju iwadii lori wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI