Ọwọ tẹ awọn ibeji ti wọn jẹ ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun l'Ọṣun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, May 6, 2023

Ọwọ tẹ awọn ibeji ti wọn jẹ ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun l'Ọṣun


Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti tẹ awọn ibeji kan, Taiwo ati Kẹhinde Adeleke tọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹtalelogun lọ lori ẹsun ṣiṣe ẹgbẹ okunkun.
 
A gbọ pe awọn ibeji yii ti wa ninu iwe awọn ọdaran ti ileeṣẹ ọlọpaa n wa tipẹ, ti wọn si lawọn lo lọwọ si bi wọn ṣe pa Abiọdun Apalara niluu Ẹsa Oke.
 
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe asiko t'awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun kọju ija sira wọn ni wọn pa Abiọdun Apalara, ti wọn si lawọn ibeji naa wa lara ikọlu ọhun.
 
Yẹmisi Ọpalọla to jẹ agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọsun nigba to n foju awọn ibeji naa han pẹlu awọn meje miran tọwọ tẹ kaakiri ilu Oṣogbo lọsẹ to kọja yii ṣalaye pe ogbologbo ni wọn.
 
O ni ẹsun to nii ṣe pẹlu digunjale, ẹgbẹ okunkun ati ipaniyan ni wọn fi kan gbogbo wọn.
 
Yatọ si awọn ibeji naa, ọwọ tun tẹ awọn bii Ojo Ayọbami, Ibrahim Qudus, ati Ojo Oretu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI