Ẹ woju awọn ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn n da ilu Ṣagamu laamu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 12, 2023

Ẹ woju awọn ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn n da ilu Ṣagamu laamu


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ awọn gendekunrin ti ko din ni mẹwaa, ti wọn jẹ ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn ti n wa tipẹ, iyẹn awọn to n da ilu Ṣagamu ati agbegbe rẹ laamu lojoojumọ.
 
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Abimbọla Oyeyẹmi lo f'idi iṣẹlẹ yii mulẹ, to si fi ye wa pe ọjọ Abamẹta tii ṣe Satide, iyẹn ọjọ kẹfa, oṣu karun-un, ọdun ti a wa yii lọwọ tẹ gbogbo wọn lahamọ wọn.

Adekọya Adeṣina, Ayinde Olumide, Adebayọ Jamiu, Ajayi Temitọpẹ, Taiwo Ọlatunji, Ọladapọ Ayeye, Johnson Adeyẹmi, Tunde Banjọ, Gbenga Mọrufu ati Tunde Adenuga lorukọ awọn tọwọ tẹ naa lawọn agbegbe ọtọọtọ to wa nijọba ibilẹ Odogbolu.
 
Ibi ti wọn ti n gbaradi lati tun lọ da ogun miran silẹ, iyẹn lati koju awọn alatako wọn la gbọ pe akara wọn ti tu s'epo.
 
A gbọ pe awọn kan lo ta ileeṣẹ ọlọpaa lolobo, ti wọn fi sare gbera lati lọ dena de wọn. Wọn ni bi wọn ṣe foju kan awọn ọlọpaa ni wọn ti koju ija si wọn, ṣugbọn ti awọn ọlọpaa naa ko ṣee lọrọ ere pẹlu wọn.
 
Mẹwaa lọwọ pada tẹ, bo tilẹ jẹ pe wọn ṣe ọkan lara awọn ọlọpaa naa, SP Morakinyọ Adejumọ leṣe kọja sisọ, ṣugbọn ti wọn sare gbe e lọ si ọsibitu, nibi to ti lọ gba itọju.
 
Lara awọn nnkan ti wọn gba lọwọ wọn ni ọta ibọn mẹjọ, ati ọpọlọpọ igbo, iyẹn egeboogi oloro ti wọn maa n mu ko to di pe wọn lọ da wahala silẹ.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Ọlanrewaju Ọladimeji ti wa paṣẹ pe ki wọn lọ foju awọn tọwọ tẹ naa ba ile ẹjọ lẹyin iwadii, ati pe ọwọ gbọdọ tẹ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun to ku, ki alaafia le tubọ maa jọba nipinlẹ Ogun ati agbegbe rẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI