Nitori omi gbigbona to da le ọmọ ọdun mẹẹdogun lori, wọn ni ki iyaale ile gba ilẹ ayika kootu fun ọjọ mọkanlelogun gbako - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 12, 2023

Nitori omi gbigbona to da le ọmọ ọdun mẹẹdogun lori, wọn ni ki iyaale ile gba ilẹ ayika kootu fun ọjọ mọkanlelogun gbako


Ile ẹjọ Majisireeti kan ti wa niluu Makurdi, ipinlẹ Benue ti paṣẹ pe ki iyaale ile kan, Doosur Samuel gba ile ayika kootu naa fun ọjọ mọkanlelogun gbako, lai ya ọjọ kan silẹ.

 
Ẹsun ti wọn fi kan Doosur, ẹni to n gbe ni Logo 1, Makurdi ni pe o da omi gbigbona le ọmọdebinrin, ọmọ ọdun mẹẹdogun lori, ti ara ọmọ naa si bo yannayanna, ẹsun ti wọn lo tako iwe ofin ọdaran nipinlẹ Benue, tọdun 2004 ni abala 248.

Bo tilẹ jẹ pe Doosur gba pe lootọ loun jẹbi, ṣugbọn ki ile ẹjọ naa foju aanu wo oun. Onidajọ Kelvin Banongo nigba to n gbe idajọ kalẹ, bu ẹnu atẹ lu iwa ti Doosur hu, to si lo ku diẹ kaato.

Onidajọ naa paṣẹ pe lati aago mẹwaa aarọ si aago mejila ọsan, bẹrẹ lati ọjọ karun-un, oṣu kẹfa, yatọ si ọjọ Aiku tii ṣe Sannde ni obinrin naa yoo fi gba ilẹ ọhun.
Bakan naa ni Onidajọ yii tun paṣẹ pe ki awọn alabojuto ọgba ẹwọn tiluu Makurdi lati ṣabojuto obinrin naa titi ọjọ mọkanlelogun yoo fi pe.
 
Agbefọba, Insp Ọmayi Ujata to fẹsun kan Doosur niwaju ile ẹjọ sọ pe ọjọ keje, oṣu karun-un, ọdun ti a wa yii ni ẹnikan to n jẹ Ene Terwase ranṣẹ s'awọn ọlọpaa lori iṣẹlẹ naa.
 
Ujata sọ pe niṣe ni Doosur kan deede da omi gbigbona le ọmọ oun, Mimidoo Samuel lori, lai ni ẹṣẹ kankan to le fi kan an. O loju ẹsẹ lawọn ti gbe ọmọ naa lọ si ọsibitu Benue University Teaching Hospital fun itọju.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI